1 / 9 Next Page
Information
Show Menu
1 / 9 Next Page
Page Background

Page 1

The Islamic Bulletin

The Purpose Of Life

E

re

idi

I

walaye

o daju pe won yi o so fun o ohun ti elomiran ti so…

Tabi ohun ti awon miran nro. Ohun ti baba mi so pe

ere idi iwalaye je, ohun ti alufa ijo mi so pe ere idi

iwalaye je, ohun ti oluko mi ni ile-iwe so, ohun ti ore

mi so.

Ti mo ba bere lowo enikeni nipa ere idi oun-

je jije, “Ki ni idi ti a fi njeun?” Opolopo eniyan yi o

dahun, ni ona kan tabi omiran, “O wa fun eto ijeemu

ara!” Nitori ounje mu wa wa laaye... Ti mo ba beere

lowo enikeni idi ti won fi n sise? Won yi o wipe, nitori

o se Pataki lati le ran ara won lowo ati pese fun awon

ebi won. Ti mo ba beere lowo enikeni idi ti won fi n

sun, idi ti won fi n we, idi ti won fi n w’oso ati bebelo,

won yi o dahun – “Awon nkan wonyi je ohun ti o se

Pataki fun gbogbo eniyan.” A le tesiwaju bayi nipa bi

beere ibeere to to ogorun, a o gbo idahun kan na tabi

iru kan na lati odo enikeni, ni ede yi o wu, nibikibi ni

aye yi! “Ki lo de, ni gba ti a ba bere ibeere yi, ‘Kini ere

idi iwalaye wa?’, ti a ma ri orisirisi idahun?” Idi ni wipe

ona awon eniyan ruju, won ko mo. Won wa ninu

okunkun. Sugbon yala ki won so wipe “Emi ko mo,”

won a kan dahun awon idahun ti o ti a ti fi si opolo

won.

E je ki a ro nipa eyi. Nje ere idi iwalaye wa

ninu aye yi kan ni lati jeun, sun, w’oso, se ise, ko

awon ohun ini jo ki a si gbadun ara wa? Nje eyi ni ere

idi wa? Kini ere idi ti a fi bi wa? Kini idi iwalaye wa,

kini ogbon to wa leyin dida ti a da eniyan ati ile aye

nla yi? E ro nipa ibeere yi!

Awon kan n jiyan pe ko si idaniloju pe se ni a

da wa, pe ko si eri pe Olorun wa, pe ko si idaniloju pe

ada ile aye yi nipa imo Olorun Kankan. Awon eniyan

wa ti won gbagbo bayi – won si ma n so wipe ile aye

kan wa be ni. Iron la dun, ile aye yi pelu ohun gbogbo

ninu re si waye bee. Won si njiyan pe iwalaye wa ko

ni idi Kankan ati pe ko si ohun kohun ti a le fi fi idi re

mule yala nipa ero wa tabi imo ijinle sayensi pe Olo-

run wa, tabi ere idi, tabi imo Kankan nipa ile aye yi.

Nibi n o ka awon ese Kankan ninu Kurani ti o

so nipa koko yi.

“Dajudaju ninu eda orun ati ile ati titele (ara won)

oru ati osan, ami mbe fun oni-lakaye. Awon eni ti

nranti ni iduro ati ni ijoko ati ni idubule won, tin

won nronu nipa iseda orun ati ile: (ti nwon wipe)

Oluwa wa! Iwo ko da (gbogbo) eyi lasan! Ogo ni fun

O! nitorina gba wa la kuro ni bi ya ina.”

[Kuran 3:

190-191]

O je ohun iwuri fun mi lati ni anfani yi lati ba yin

soro ni ibi yi. Mo si fe so fun yin pe eyi ki I se idani-

leko… Mi o ro pe mo wa ni igbaradi lati dan’leko.

Sugbon o je bi…amoran fun ara mi paapaa. Nitori

mo ri ara mi gegebi ookan ninu awon ti o joko si ori

awon aga wonyi ni iwaju mi. Ni iwon ojo die seyin,

ni iwon odun die seyin, ni iwon igba die seyin – mo

joko ni ibi kan na nibi ti e wa yi, orile ede yi o wu tie

ti le ti wa - ko ni fi se. Mo je eniyan ti ko mo nkank-

an nipa Islam. Ati ni igba yi, mo je enikan ti ko ni

oye… sere idi iwalaye!

Nitori idi eyi, mo bebe pe ki e ri ohun ti mo

n so loni gegebi alaye ati imoran – ki si I se bi idani-

leko. Imo naa ti mo fe pin pelu yin, o le da bi eni pe

o fe po die. Ni gba ti e ba ye idiwon agbara opolo

eniyan wo ati iwon oye imo ti o le fi pamo – e o ri

wipe iwonba alaye ti mo fe se loni, ko le d’erupa yin.

Ojuse mi ni lati soro nipa awon koko ijiro-

ro wa toni – ki ni ere idi iwalaye wa? Ati pelu ki n

bere ibeere yi – “Ki llo mo nipa esin Islam?” Eyi ni

ni wipe – kini ohun ti o mo ni pato nipa Islam? Ki I

se ohun ti o ti gbo nipa Islam; Ki I se ohun ti o ti ri

gegebi iwa awon Musulumi kan, sugbon – ki ni o mo

nipa Islam?

O je ohun iwuri fun mi lati ni anfani yi, mo si fe

beere nipa siso wipe gbogbo yin pata ni e ni ojuse

kanna… Ojuse yi si nip e ki e f’eti sile tabi ka a –

pelu okan ti a si sile.

Ninu aye yi ti o kun fun ojusaju ati orisirisi asa, o je

ohun ti o soro lati ri eniyan ti o le ya akoko soto lati

ronu. Lati ro arojinle nipa iwalaye, lati gbiyanju lati

wadi otito nipa aye yi ati ere idi toto ti iwalaye wa.

Sugbon o se ni laanu wipe ni igba ti e ba bi awon

eniyan leere ibeere yi – “Kini ere idi iwalaye wa?” eyi

ti o je ibeereti o se koko ti o si se pataki julo, won ki

yi o so fun o ohun ti won ti ri tabi ro. Ni opo igba,