Previous Page  8 / 9 Next Page
Information
Show Menu
Previous Page 8 / 9 Next Page
Page Background

Page 8

The Islamic Bulletin

The Purpose Of Life

oluso agutan, ti a bi ti o si dagba ni aginju lai le ko tabi

ka—bawo ni o sele se alaye awon nkan wonyi ti ko ri

ri.

Ipa to yato ju lara Kuran ni wipe o fi idi awon

iwe mimo ti isaju mule. Atipe, lehin ti o ba ye esin

Islam wo, o gbodo pinnu lati di Musulumi, o ko nilo

lati ro a ti paaro esin re! O ko paaro esin re… Wo, ti

o ba jo, o ko ni so aso owo iyebiye $500 nu—o ko ni

soonu! Wa mu lo ba telo wa si so fun ko ba e mu ko

le wo o. Bakanna ni pelu igbagbo re, ola re, ife re , ife

ti o ni si Jesu Kristi, isopo resi Olorun, ijosin re, isotito

re ati ifaraji re si Olorun Oba – o ko ni so eyi nu! Wa

di eyi mu! Sugbon, wa se atunse ni awon ibi ti o mo

pe a ti fi otito han fun o! O tan!

Islam rorun: lati jeri pe ko si elomiran to to fun

ijosin lehin Olorun atobiju. Ti mo ba bere lowo enike-

ni ninu yin lati jeri pe baba ohun ni baba oun—melo

ninu yin lo ma so wipe, ‘beeni, baba mi ni baba mi;

Omo mi ni omo mi; Aya mi ni aya mi; Emi na si ni

emi.’ Bawo ni o se waje ti o nira fun yin lati jeri pe

okan ni Atobiju ati wipe Olorun Atobiju Oun nikan,

ati wipe Olorun Atobiju ni Oluwa re ati Eleda re? Ki lo

de ti O gbe raga lati se eyi? Nje O n s’ogo ninu ara re?

Nje O ni ohun kan ti Olorun ko ni? Tabi, O o do juru

fun o? Eyi ni ibeere ti O ni lati bere lowo ara re.

Ti o ba ni anfani lati s’eto ohun gbogbo pelu eri

okan re, ati lati s’eto ohun gbogbo pelu Olorun, nje

iwo yi o se be? Ti iwo ba ni anfani lati so fun Olorun

ko gba eyi ti o dara ninu iwa ati ise re, nje iwo yi o se

be? Ti iwo ba ni anfani lati se eyi ki o to ku, ti o siro

pe iwo yi o ku ni ale yi, nje iwo ki yi o kia jeri naa pe

Olorun kan soso ni o wa? Ti o ba ro wipe iwo yi o ku

ni ale yi ati pe ni iwaju re yi aljanna ati ni eyin re ina

apadi, nje iwo ki yi o kia jeri pe Muhamadu ni ojise

ikehin ti Olorun ati asoju gbogbo awon anabi? Iwo ki

yi o kia jeri pe O je okan ninu awon ti a ko oruko won

sile ninu iwe Olorun gegebi awon ti yonda ara won!

Sugbon, o lero wipe o si ni odun die lati gbe si.

Ati pelu, o ko se tan lati maa gbadura lojojumo! Idi e

ni wipe o lero wipe o si ni odun die lati gbe si. Sugbon

melo ni ‘odun die?’ O to igba wo sehin ti ori re kun

fun opolopo irun? O to igba wo sehin ti gbogbo irun

ori re je dudu? Nisiyi, o ni irora ni orukun ati ejika re

ati ni awon ibi omiran! O to igba wo sehin ti o si je

omode, ti o n sare kiri ati ti on sere kiri lai ni ohunko-

hun lati ro? O to igba wo sehin? Ana ni! Beeni. Iwo yi

o si ku l’ola. Nitorina, igba melo si ni o fe fi duro?

Isalm jeri pe Olorun alagbara julo ni Olorun,

Olorun kan soso, Oun nikan ti ko l’obakan. Islam

jeri pe awon malaika wa ti a ran jade pelu ise ifihan

si awon anabi. Gbigbe awon ise iranse lo fun awon

anabi. Di dari awon afefe, awon oke nla, awon okun,

ati gbigba emi awon ti Olorun ni akoko won ti to lati

ku. Islam jeri pe gbogbo awon anabi ati ojise Olorun

je eniyan olododo. Ati wi pe a ran won jade lati odo

Olorun oba lati so fun gbogbo eniyan gbe ojo idajo

kan nbo fun gbogbo eda. Islam jeri pe, ati ibi ati ire

gbogbo wa ni ikawo Olorun atobiju. Ni akotan, Islam

jeri pe dajudaju igbende (ajinde) nbe lehin iku.

Islam da bi ile nla. Gbogbo ile ni a si gbodo

ko pelu ipinle ati opomulero lati gbe ile naa duro.

Opomulero ati ipinle kan. O si gbodo ko ile pelu

awon ilana.

Awon ojuse ti o ye gbogbo Musulumi je ohun

ti ko le rara, won si wa ni isori marun pere, eyi ti a

mo si awon opo marun ti Islam: Igbagbo, Ijosin, Awe,

Itore ati Irin ajo lo si ile mimo.

Eyi ti o se Pataki julo ninu liana Islam ni lati gbe ig-

bagbo ninu Olorun kan soso ro. Eyi ni pe, lati ma gba

olorun miran pelu Olorun. Lati ma se josin fun ohun

miran lehin Olorun. Awon janma maa josin fun Olo-

run tara ki ise nipa se awon alufa tabi woli tabi eniyan

mimo. O ko gbodo so ohunkohun nipa Olorun eyi

ti o ko ni eto lati so. Lati ma se so wipe ‘o ni baba,

omokunrin, omobinrin, iya, egbonkunrin, egbonbin-

rin, igbimo isakoso.’ Lati ma so ohunkohun nipa Ol-

orun eyi ti o ko ni eto lati so. Ni igba ti o ba jeri, o se

idajo fun ara re. O se idajo eyi ti o fe. Yala ko se idajo

fun are re lo si Alafia ati aljanna, tabi ki o se idajo fun

ara re lo si idojuru, iponju, ina apadi ati ijiya. O se

idajo fun ara re.

Nitorina, bere lowo ara re, “Nje mo gbagbo pe

Olorun kan soso ni o wa?” Ni igba ti o b a bere ibeere

yi lowo ara re, o gbodo dahun, “Beeni, Mo gbagbo.”

Wa beere ibeere ti o tele. Nje mo gbagbo pe Mu-

hamadu ni ojise Olorun atobiju? “Beeni, Mo gbagbo.”

Ti o ba gbagbo bayi, o ti di Musulumi. O ko nilo lati yi

ohun ti o je pada. O kan nilo lati se atunse si ohun ti o

je—ni ero re ati ise re.

Ni akotan, Mo beere ibeere kan pato: Nje oye

ohun ti mo so fun yin ti ye yin? Ti o ba ti gba awon

ohun ti mo so, O ti setan lati di Musulumi. Lati di

Musulumi, o gbodo koko ka Shahada “Ijeri”; eyi ni lati

jewo igbagbo re ninu Isokan Olorun ati igbagbo ninu

Muhamadu gegebi anabi Olorun.

لا إله إلا الله محمد رسول الله

La ilaha illa-Allah, muhammad rasullulah

Ko si olorun miran lehin Olorun, Muhamadu si ni

ojise Olorun.

Mo jeri pe Olorun kan soso lo wa

Mo jeri wipe Muhamadu ni ojise Olorun.

Wo fidio ti o tele yi:

http://www.islamicbulletin.org/purpose/shahada/sh_yoruba.mp4