Nini oye nipa Islam ati awon Musulumi

Kini Islam?

Tani awon Musulumi?

Kini awon Musulumi gbagbo?

Bawo ni eniyan se le di Musulumi?

Kini itumo ‘Islam’?

Nje Islam ati esin Krstiani wa lati orisun ti o yato?

Kini Ka’ba?

Tani Muhamadu?

Bawo ni Muhamadu se di annabi ati ojise Olohun?

Bawo ni itankale Islam se ni ipa ni agbaye?

Kini Kuran?

WKini Kuran wa nipa?

Nje awon orisun Atokewa miran tun wa?

Kini awon ‘Opo Marun’ ti esin Islam?

Nje Islam fi aye gba awon esin miran?

Kini awon Musulumi nro nipa Jesu?

Kilo de ti ebi fi se Pataki fun awon Musulumi?

Bawo nipa awon obinrin Musulumi?

Nje Musulumi le ni ju aya kan lo?

Nje igbeyawo ninu Islam dabi ti awon Kristiani?

Bawo ni awon se nse itoju awon agba?

Bawo ni awon Musulumi se ri iku?

Kini Islam so nipa ogun?

Nipa ounje nko?

Bawo ni Islam se fi idi eto omo eniyan mule?

Islam ni Orile-ede Amerika

Aye Awon Musulumi


Kini Islam?

Islam ki I se esin titun, sugbon otito kan soso naa ti Olohun fihan fun gbogbo eniyan nipase awon annabi. Fun idakan ninu marun awon eniyan, Islam je esin ati ona igbesi aye ti o kun. Awon Musulumi ntele esin alaafia, aanu, ati idariji, ati opolopo ko si ni ohunkohun nse pelu awon iwa ipekun ati ipa ti o ti di mi mo pelu esin Islam.


Tani awon Musulumi?

Awon Musulumi ngbadura ni
Jerusalemu ni ita Ile ori Apata.
Ara Morocco kan ngbadura.

Egberun lona egberun lona egberun kan eniyan lati orisi eya, orile ede ati asa kaakiri agbaye – lati iha gusu Philippines titi de Nigeria – ni a sopo sokan nipa esin kan Islam. Ida mejidinlogun ninu ogorun ngbe ni ile Arabi; awujo awon Musulumi ti o poju wa ni Indonesia; opolopo ibi ni Asia ati Africa lo je Musulumi, be si ni opolopo awon ipin-kekere wa ni Soviet Union, China, Ariwa ati Gusu Amerika, ati Europe.


Kini awon Musulumi gbagbo?

Awon Musulumi gbagbo ninu Olohun Okan, Ailegbe, ati ti ko lakawe; ninu awon Angeli ti O da; ninu awon annabi ti o ti ipase won fi ifihan re han fun awon eniyan; ninu ojo idajo ati ninu isiro olukaluku fun ise owo re; ninu ase Olohun lori ayamo eniyan ati ninu aye lehin iku. Awon Musulumi gbagbo ninu awon isisentele awon annabi bere lati ori Adamo ati pelu Noa, Ibrahimu, Ishmaeli, Isaaki, Jakobu, Josefu, Jobu, Mose, Aaroni, Dafidi, Solomoni, Elija, Jona, Johanu onitebomi, ati Jesu, ki alaafia wa pelu won. Sugbon ise iranse Olohun ti o kehin fun eniyan, ti o je akotan gbogbo ise iranse ti isaju ni a fiihan fun Annabi Muhamadu lati owo Gabrieli.


Bawo ni eniyan se le di Musulumi?

Nipa si so pe ‘ko si olohun yato si Olohun, atipe Muhamadu ni ojise Olohun.’

 

Nipa ijewo yi, onigbagbo jewo igbagbo re ninu gbogbo ojise Olohun, ati iwe mimo ti won mu wa.


Kini itumo ‘Islam’?

Oro Larubawa ‘Islam’ tumo si ‘iyanda’, o si wa lati inu oro kan ti o tumo si ‘alaafia’. Ninu oro esin o tumo si iyanda ara eni patapata si ife Olohun. ‘Esin Muhamadu’ ko bo si rara nitori eyi yi o tumo si wipe awon Musulumi nsin Muhamadu, won ko si Olohun. ‘Allah’ ni oruko Olohun ni ede Larubawa,o je eyi ti awon Arabi sin lo yala Musulumi tabi Kristiani.


Nje Islam ati esin Krstiani wa lati orisun ti o yato?

Rara. Papo pelu esin Judaism, won wa lati odo annabi ati baba nla Abrahamu, awon annabi esin meteta si wa lati odo re Muhamadu lati lati odo akobi Ishmaeli, Mose ati Jesu lati odo Isaaki. Abrahamu te ilu na ti a mo si Moka loni yi do, oun ni o ko Ka’ba ti gbogbo Musulumi ma nkoju si ni igbati won ba ngbadura.


Kini Ka’ba?

Makah, Saudi Arabia

Ka’ba je ibi ijosin ti Olohun palase fun Abrahamu ati Ishmaeli lati ko fun bi egberun odun merin sehin. A ko ibi ijosin pelu okuta lori ibi ti opolopo ka si ibi mimo kan ti Adamo ti da sile. Olorun pase fun Abrahamu lati pe gbogbo awon omo eniyan lati wa si ibi ijosin naa, ti awon aririn ajo mimo ba si lo si I be loni won a ni ‘Ni ijosin Re, Oluwa’, ni idahun si ipe Abrahamu. wa si ibi ijosin naa, ti awon aririn ajo mimo ba si lo si I be loni won a ni ‘Ni ijosin Re, Oluwa’, ni idahun si ipe Abrahamu.


Tani Muhamadu?

A bi Muhamadu ni odun 570, ni igba ti esin Kristiani ko I ti fi ese mule daradara ni ile Europe. Nitori baba re ti ku siwaju ibi re ati iya re ni odun die lehin ibi re, a to dagba ni odo arakunrin baba re lati eya Quraysh. Bi o ti ndagba o di eni mi mo fun iwa otito re, isore ati isododo re, nitorina, won ma n wa kiri lati ba won petu si aawo. Awon onkotan pe ni oniwa tutu ati alorojinle.

Muhamadu je eni ti o kudun esin gidigan, o si korira iwa ibaje ti o wa ni awujo. O di iwa re lati maa lo se arojinle ninu iho ti o wa ninu apata Hira ni itosi Jabal al-Nur, ‘Ori Oke Imole’ ni itosi Makah.


Bawo ni Muhamadu se di annabi ati ojise Olohun?

Mosalasi Annabi, Madinah, ile yi fi ibi ti ile re wa ati ibi ti a sin si han.

Ni eni ogoji odun, ni igba kan ti o wa ninu ironujinle re, Muhamadu gba ifihan re akoko lati odo Olohun lati owo Malaika Jubril. Ifihan yi, ti o te siwaju fun ogun odun o le meta, ni a mo si Kuran.

Gele bi o ti bere si ni ka awon oro ti o gbo lati enu Jubril, ati lati maa waasu awon otito ti Olohun ti fi han fun, oun ati awon omo lehin re dojuko inunibini kikoro, ti o le debi wipe ni odun 622, Olohun palase fun won lati jade lo kuro ni ilu. Isele yi, Hijra, ‘ijadelo’, ninu eyi ti won kuro ni Makah lo si ilu Medinah ni iwon 260 maili ariwa, je ibere odun awon Musulumi.

Ori Oke Imole ni ibi ti Gabrieli ti
wa ba Annabi Muhamadu.

Lehin opo odun, Annabi ati awon omo lehin re ni anfani lati pada lo si Makah, nibiti won ti foriji awon ota won ti won si fi ese Islam mule gidi. Ki Annabi to ku ni eni odun meta-le-logota, opolopo Arabia ni o ti di Musulumi, ni aarin ogorun odun lehin iku re, Islam ti tan ka titi de Spaini ni iwo orun ati titi de ila orun ni China.


Bawo ni itankale Islam se ni ipa ni agbaye?

Taj Mahal, India.

Ninu awon idi fun idagbasoke ati itankale Islam ni ona alaafia je irorun eko re – Islam npe fun igbagbo ninu Olohun kan soso ti o ye fun ijosin. O si nro awon eniyan kikankikan lati lo agbara imo ati akiyesi won.

Mosalasi Hui Shen, China.
Ti a ko ni 7th Century.

Laarin odun die, olaju nla ati ile-eko giga julo nfese mule, nitori gegebi Annabi se so, ‘wiwa imo je ojuse fun gbogbo Musulumi yala okunrin tabi obinrin’. Ifowosowopo imo ati ero lalti Ila Orun ati Iwo Orun mu ki aseyori nla waye ninu imo ilera, imo isiro, imo aye, imo ofurufu, ikole, iwe, ati itan. Opolopo eto ti o se pataki bi algebra, eto onka Larubawa, ati ero ofifo (eyi ti o je pataki fun ilosiwaju isiro), ni a mu lo si Europe nipase Islam. Awon irinse nla ti o mu ki o seese lati se awon awari ti won se ni Europe di sise fun apeere, ilodisi, ati mapu itoka daradara.


Kini Kuran?

Kuran je akosile awon oro Olohun ti a fihan lati owo Malaika Jubril si Annabi Muhamadu. Muhamadu ha si ori o si ka fun gbogbo awon ti o wa pelu re, o si di kiko sile lati owo awon akowe, ti won ye e wo ni igba aye re. Ko si eyikeyi ninu Ori 114, Suras, ti a ti yipada lati opo ogorun odun sehin, nitorina, Kuran ni gbogbo ona yato o si je iwe iyanu ti a fihan fun Muhamadu lati ogorun odun merinla sehin.

Ori iwe akoko ti Kuran, Fatiha, je adura ti o se pataki ninu Islam.
O kun fun koko Kuran a si ma nka a ni gbogbo adura.

Kini Kuran wa nipa?

Kuran, oro Olohun ti a fihan kehin, je orisun akoko fun igbagbo ati iwuwasi gbogbo Musulumi. O me nu ba gbogbo koko ti o ni se pelu wa gegebi eniyan: ogbon, eko, ijosin, ati ofin, sugbon koko Pataki inu re ni ibasepo laarin Olohun ati awon iseda Re. Bakanna, o pese ilana fun a ti ni awujo ti o dara, iwa eniyan ti o dara ati eto isuna ti o peye.


Nje awon orisun Atokewa miran tun wa?

Beni, sunna, apeere ati iwuwasi Annabi, je ilana keji fun awon Musulumi. Hadith je iroyin ti o se fokantan awon nkan ti Annabi so, se, tabi fi owo sile. Igbagbo ninu sunna je ipa kan ninu igbagbo Islam.

Apeere awon oro Annabi

Annabi so wipe:

‘Olohun ki I se aanu fun enikeni ti ko se aanu fun awon elomiran.’

‘Enikeni ninu yin ko I ti gbagbo ayafi igba ti o ba ro si omolakeji ohun ti o ro si ara re.’

‘Eni ti o jeun ti o yo ni igba ti ara adugbo re wa lai rounje je ki I se onigbagbo.’

‘Onisowo olotito ti o si se fokantan je eni ti a mo mo awon annabi eniyan mimo, ati awon ajeriku’

‘Alagbara ki I se eni ti o gbe elomiran lule bikose eni ti o le ko ara re nijanu ni igba ti inu ba nbi.’

‘Olohun ki I dajo nipa imura tabi irisi re sugbon O nye okan re wo o si n wo iwa re.’

‘Okunrin kan nrin ni ona kan ongbe si ngbe. Nigba ti o ri konga kan, o sokale ti, o mu amuyo o si goke wa. Nigbana o ri aja kan ti ongbe ngbe ti o ngbiyanju lati la ere lati pa ongbe re. Okunrin yi ri wipe aja yin la koja ohun ti oun ti la koja tan, nitori naa o tun sokale lo, o bu omi kun inu bata re o si gbe jade wa fun aja naa lati mu. Olohun se aforiji awon ese re nitori iwa yi.’ A beere lowo Annabi: ‘Ojise Olohun, nje a o pin wa lere fun iserere wa si awon eranko?’ O dahun wipe, ‘Ere wa fun iserere si gbogbo ohun abemi.’

Lati inu awon akojo hadith ti Bukhari, Musulumi, Tirmidhi ati Bayhaqi.

Kini awon ‘Opo Marun’ ti esin Islam?

Won je opomulero igbe aye Musulumi: igbagbo, adura, itoju awon alaini, ise ara-eni ni mimo, ati irin ajo lo si Makah fun awon ti o ni agbara re.

1. IGBAGBO

Shahada ni a ko si enu ona abawole si Aafin Ottoman Topkapi (ile-ona Ni
ewu kan ti Annabi wo, ati awon ohun isura miran), ni Istanbul.

“Ko si olohun to to fun ijosin ayafi Olohun atipe Muhamadu si ni ojise Re.”

Ijewo igbagbo yi ni a npe ni Shahada, agbekale ti o rorun ti gbogbo onigbagbo nke. Ni ede Larubawa, ipa akoko ni: La ilaha illa Llah – ‘ko si olohun miran lehin Olohun’; ilaha (olohun) le toka si ohunkohun ti a le fi si ipo Olohun – oro, agbara, ati bebelo. Lehin eyi illa Llah: ’lehin Olohun’, orisun gbogbo iseda.

Ipa keji Shahada ni Muhammadun rasulu’Llah: ‘Muhamadu ni ojise Olohun.’ Eko itosona ti wa lati ipase eniyan bi ti wa.

 

2. ADURA

Salat ni oruko adura aigbodomase marun ti a nse lojojumo, won si je ona taara laarin olujosin ati Olohun. Ko si eto ase ninu Islam, ko si alufa, nitorina, eniyan ti o ba ni imo Kuran ti a ba si yan lati owo ijo ni o ma ndari adura naa. Awon adura mararun yi kun fun ese lati inu Kuran, a si ma nke won ni ede Larubawa, ede ti a fi se ifihan naa, sugbon olukaluku le beere edun okan re ni ede ara re.

A ma nse adura ni aaro kutukutu, ojokanri, osan, irole ati ni asale, nitorina a gbe liana ojo kale. Bo ti le je wipe o dara ki a jo jumo josin papo ninu Mosalasi, Musulumi le gba adura ni ibikibi, gegebi ori papa, yara ise, ile ise, ile eko. Enu ma nya awon alejo si orile-ede awon Musulumi bi adura se je ohun Pataki ninu aye awon Musulumi.

New Mexico, U.S.A.
Ipe si Adura lati Mosalasi Abiquiu.

 

Itumo Ipe si Adura:

Olohun ni atobiju. Olohun ni atobiju.
Olohun ni atobiju. Olohun ni atobiju.
Mo jeri wipe ko si olohun miran ayafi Olohun.
Mo jeri wipe ko si olohun miran ayafi Olohun.
Mo jeri wipe Muhamadu ni ojise Olohun.
Mo jeri wipe Muhamadu ni ojise Olohun.
Wa si adura. Wa si adura.
Wa si aseyori (ni aye yi ati aye ti nbo)!
Wa si aseyori!
Olohun ni atobiju. Olohun ni atobiju.
Ko si olohun ayafi Olohun.

3. ITORE

Itore ma nje ki owo po si ni awujo, Cairo

Okan Pataki ninu awon eko Islam ni wipe ohun gbogbo je ti Olohun, ati nitorina, oro ti a ba ni je ohun ti Olohun toju si wa lowo. Oro yi zakat tumo si ‘isodimimo’ ati ‘idagbasoke’. Awon ohun ini wa di mimo ni igba ti a ba ya apa kan soto fun awon alaini, ati, bi igba ti a ba ge awon ohun ogbin ki o le wu dada, yiya soto ma nmu iwontuwonsi wa o si ma nmu idagbasoke wa.

Okankan Musulumi ni yi o siro zakat tire fun ara re. Ni opo igba eyi tumo si sisan ida meji ati abo ninu ogorun owo eniyan lododun.

Eniyan daradara le pinfunni bi o ba se wu gegebi sadaqa, o dara ki o si se eyi ni ikoko. Botileje wipe a le tumo oro yi si ‘ipinfuni atokanwa’ o ni itumo ti o jinle ju eyi lo. Annabi so wipe ‘pipa de arakunrin re pelu erin eye papa je itore.’

Annabi so wipe:

‘Itore je ojuse Pataki fun gbogbo Musulumi.’ A bi wipe: ‘Ti eniyan ko ba ni nkankan nko?’ Annabi dahun wipe: ‘Ki o sise pelu owo re fun anfani ara re ki o si wa pin ninu ohun ti o ba pa fun itore.’ Alabarin naa bere wipe: ‘Ti ko ba le se ise nko?’ Annabi wipe: ‘Ki o ran awon talaka ati alaini lowo.’ Awon alabarin naa tun beere siwaju pe ‘Ti ko ba le se eyi naa nko?’ Annabi dahun ‘Ki o ro awon elomiran lati se rere.’ Awon alabarin naa so wipe ‘Ti ko ba ni eyi naa nko?’ Annabi so wipe ‘Ki o so ara re kuro ninu ibi sise. Itore naa ni eyi.’

4. AWE

Ni ododun ni osun Ramadan, gbogbo Musulumi ma ngbawe lati owuro titi di igba ti oorun ba wo, nipa yiye ra fun ounje, mimu, ati ibalopo lokolaya. Awon ti o nse are, awon agba, tabi eniti o nrin irin ajo, awon obinrin aboyun tabi ti o ntoju omo ni a gba laaye lati ja awe won ki won si san pada ni igba miran ninu odun naa. Ti won ko ba ni okun lati se eyi, won gbodo bo alaini kan fun ojo Kankan ti won ba je. Awon omode yi o bere si ni gba awe (ati lati kirun) lati igba ti won ba ti balaga, sugbon won le bere siwaju akoko yi.

Botile je wipe awe je ohun ti o ni anfani fun ilera ara eniyan, o je ona kan gbogi lati se iwe ara eni mo. Nipa yiya ara eni soto kuro ninu awon ohun itura aye yi, bo tile je fun akoko die, eni ti o ngbawe yi o le mo iriri ti eni ti ko ri ounje je la koja pelu idagbasoke nipa ti emi.

5. IRINRIN AJO (Hajj)

Awon arinrin ajo nse adura ni mosalasi ni Mokah.

Irin ajo ododun lo si Mokah – Hajj – je ojuse kiki fun awon ti won ni anfani yala nipa tara ati owo lati lo. Sibe, eniyan ti o poju egberun lona egberun meji lati gbogbo origun agbaya ni o ma nlo si Mokah lati odun kan si omiran, eyi si npese anfani fun awon orile-ede yi lati pade ara won. Botile je wipe Mokah ma nkun fun awon alejo, Hajj ododun yi ma nbere ni osun kejila ti Islam (ti ise ti osupa, ki I se t’oorun, eyi to fi je wipe Hajj ati Ramadan ni igba miran ma nbo si igba ooru, igba miran a si bo si igba otutu). Awon arinrin ajo ma nwo aso ara oto: awon aso kekere ti o mu iyato asa tabi ipo kuro, ki gbogbo eniyan le wa niwaju Olohun dogba.

Ago awon arinrin ajo ni igba Hajj.

Lara awon eto Hajj, eyi ti o ti wa lati igba Abrahamu, ni yiyi po Ka’ba ni igba meje, ati lilo ni igba meje laarin awon oke Safa ati Marwa gegebi Hagari se se ni igba ti o nwa omi. Lehin eyi awon arinrin ajo a duro ni ibi petele Arafa won a si darapo mo adura si Olohun fun idariji, ni eyi ti o duro gegebi apeere Idajo Ikehin.

Ni awon opo odun sehin, Hajj je ohun ti o soro lati se. Sugbon, loni, Saudi Arabia npese opolopo pelu omi, eto irina ode oni, ati eto ilera ti o ku oju iwon.

A ma nmu Hajj wa si opin pelu ayeye kan, Eid al-Adha, ti a ma nse pelu adura ati pipin ebun ni awon awujo awon Musulumi ni ibi gbogbo. Eyi ati Eid al-Fitr, ayeye ti a fi nsa mi si opin Ramadani, je awon ayeye Pataki fun odun awon Musulumi.


Nje Islam fi aye gba awon esin miran?

Kuran so wipe:

Olohun ko ko fun nyin nipa awon eniti nwon ko ban yin jagun nipa esin tin won ko si le nyin jade kuro ninu ile nyin, pe ki e mase ore fun won ati ise dede si won. Dajudaju Olohun feran aon oluse dede.

(Kuran 60:8)

O je okan ninu awon ojuse ofin Islam lati dabo bo eto awon eni ti ko n’ikimi l’awujo, eyi ni idi ti awon ibi ijosin awon eni ti ki I se Musulumi fi po kaakiri awon orile-ede awon Musulumi. Itan fi han wa opolopo apeere bi awon Musulumi se fi aye gba awon esin yoku: ni igba ti kalifa Omaru wo Jerusalemu ni odun 634, Islam fi aye gba awon esin miran lati josin ninu ilu naa.

Ofin Islam si tun fi aye gba awon ti ki I se Musulumi lati da ile-ejo ti won sile, ati lati lo awon ofin ebi ti awon wonyi gbe kale fun ara won.


Kini awon Musulumi nro nipa Jesu?

Awon Musulumi bowo won si paya Jesu, atipe won nreti Bibo Re L’ekeji. Won ri gegebi okan ninu ojise nla Olohun si awon omo eniyan. Musulumi Kankan ki I pe ni ‘Jesu’ lasa, sugbon won ma nfikun wipe ‘alaafia wa pelu re’. Kuran fi idi ibi wundia re mule (ori Kuran kan wa pelu akole ‘Maria’), atipe Maria je obinrin mimo julo ninu gbogbo iseda. Kurani se apejuwe ibi Jesu gegebi:

‘NIgbati Malaika wipe: Ire Mariyama, dajudaju Olohun ti sa o lesa O si ti fo o mo, O si tun sa o lesa lori awon obinrin aiye. Iwo Mariyama. Tele ti Oluwa re ki o si ma foribale ki o si maa teriba pelu awon ti nteriba. Ire Mariyama, dajudaju Olohun fun o ni iro-idunnu pelu gbolohun kan lati odo Re wa, enikan to oruko re yio maa je Masihu Isa omo Mariyama, abiyi ni ni aiye ati ni orun, yio ma be ninu awon ti a sunmo (Olohun).’

‘O wipe: Oluwa mi, bawo ni omokunrin kan yio se ma be fun mi , nigbati abara kan ko fowokan mi? On (Malaika) si wipe: Bayi ni Olohun nse eda ohun ti o ba fe. Nigbati o ba pinnu oran kan yio wi fun pe: Jebe, yio si je be.’

(Kuran 3:42-47)

A bi Jesu ni ona iyanu pelu agbara kanna ti o mu Adamo wa laini baba:

Dajudaju, apejuwe Isa ni odo Olohun o dabi apejuwe Adamo; O se eda re lati inu erupe, lehinna O wi fun u pe: Je be, o si je be.

(Kuran 3:59)

Ni igba igbe aye annabi re, Jesu se opolopo ise iyanu. Kurani so fun wa wipe o so wipe:

Emi de wa ba nyin pelu ayah kan lati odo Oluwa nyin pee mi yio ya aworan kan fun nyin lati inu amo gegebi aworan eiye, emi yio si fe (ategun) sinu re ti yio si di eiye pelu ase Olohun, emi yio si maa wo awon afoju san ati awon adete, emi yio si maa so oku di alaye pelu ase Olohun.

(Kuran 3:49)

Yala Muhamadu tabi Jesu, ko si eyi ti o wa lati se ayipada si eko igbagbo ninu Olohun kan soso, ti a mu wa lati owo awon annabi isaju, sugbon lati fi idi re mule. Ninu Kuran, a ko wipe Jesu so wipe oun wa:

Ati olujeri ododo si ohun ti mbe siwaju mi ni At-Taorata ati ki emi le se ni eto fun nyin apakan ti a ti se ni ewo fun nyin; emi si wa ba nyin pelu ami kan ti o ti odo oluwa wan yin wa, nitorina e beru Olohun ki e si tele mi.

(Kuran 3:50)

Annabi Muhamadu so wipe:

Enikeni ti o ba gbagbo pe ko si olohun bikose Olohun, ohun nikan laisi alabasisepo, wipe Muhamadu ni ojise Re, wipe Jesu je eru ati ojise Olohun, oro Re mi si inu Maria ati emi kan njade lati odo Re, atipe Paradise ati Ina Apadi je otito, ni Olohun yi o tewogba si Orun.

(Hadith lati owo Bukhari)

Kilo de ti ebi fi se Pataki fun awon Musulumi?

Ebi je ipinlese awujo awon Musulumi. Alaafia ati abo ti ebi Kankan npese je ohun ti o se Pataki ti o si se koko fun idagbasoke ti emi awon eniyan ebi naa. Awujo ti o ni eto ati ife seese nipase nini awon ebi nla; awon omode je ohun isura, won ko si nkuro nile ayafi igba ti won ba se igbeyawo.


Bawo nipa awon obinrin Musulumi?

Islam ri obinrin kankan, yala omidan tabi adelebo gegebi eniyan ni aye ara re, pelu anfani lati ni ati lati lo ohun ini ati ere re. Owo ori aya ni oko ma fun aya fun ilo ara re, yi o si maa lo oruko ebi re kaka ki o gba oruko ti ebi oko re.

Ati okunrin ati obinrin ni a nreti wipe ki won wo aso ni ona ti o bojumo ti o si buyi kun eniyan; asa iwoso awon obinrin ni awon orile-ede awon Musulumi ni opo igba je asa iwoso ni awon ilu naa.

Ojise Olohun so wipe:

‘Eni pipe julo ninu awon onigbagbo ni eni ti o ni iwa dada ti o si se daradara si aya re.’


Nje Musulumi le ni ju aya kan lo?

Esin Islam je esin ti a fihan fun gbogbo awujo ati fun gbogbo igba nitorina o fi aye gba orisirisi asa ati eto. Idi le wa ti yio mu eniyan lati fe aya omiran, anfani eyi wa, sugbon kiki ki oko lo se ojuse re si awon aya naa dada.


Nje igbeyawo ninu Islam dabi ti awon Kristiani?

Igbeyawo Musulumi ki I se ‘majemu’, sugbon o je eto labe ofin ninu eyi ti awon eni mejeji ni anfani lati fi eyikeyi ipo ti o ba wu won sile. Asa igbeyawo yato lati orileede si orile-ede. Ni idi eyi, ikosile ko wopo, sugbon ki I se ohun aigbodomase ti o ba di dandan ki o waye. Ninu Islam, a ko le fi ipa fi omobinrin loko: awon obi re kan le fi iru awon omokunrin ti o le fe han-an.


Bawo ni awon se nse itoju awon agba?

Ni awon orile-ede awon Musulumi ko si ohunkohun bi ile itoju awon agba. Ise to wa ninu sise itoju awon arugbo wa nigba isoro aye won je ohun ti a ka si ola ati ibukun, ati anfani fun idagbasoke nipa ti emi. Olohun ko fe ki a gbadura fun awon obi wa nikan, sugbon ki a se si won pelu ife ti ko lodiwon ni iranti wipe ni igba ti a je omode, won se itoju wa ju ara won lo. Awon iya je eni aponle julo: annabi ko wa wipe ‘Paradise nbe l’ese awon iya’. Ni igba ti won ba d’arugbo, awon obi Musulumi ni a ma ntoju pelu aanu, iwa rere ati ifaraji.

Ninu esin Islam, sise ise sin awon obi eni je ojuse ti o se ikeji si adura nikan, o si je eto won lati reti eyi. O je ohun irira lati korira awon obi wa nigba ti won ba ti dagba tan ti o si soro fun lati le ran ara won lowo.

Kurani so wipe: ‘Atipe Oluwa re ti palase pe: E ko gbodo sin kinikan ayafi On nikan ati ki e ma se rere fun awon obi mejeji. BI okan ninu won ba dagba si o lowo abi awon mejeji, o ko gbodo se sio won be si ni o ko gbodo jagbe mo won, sugbon ki o ba won soro alaponle. Ati ki o re ara nile fun won niti anu ati ki o ma sope: Oluwa, (ba mi) ke awon mejeji gegebi nwon ti re (ke) mi ni kekere.

(Kuran 17:23-24)

Bawo ni awon Musulumi se ri iku?

Gegebi awon Ju ati Kristiani, awon Musulumi gbagbo wipe ile aye yi je igbaradi fun aye ti nbo wa. Ninu awon koko igbagbo ni: Ojo Idajo, ajinde, Oorun ati Ina Apadi. Ti Musulumi ba ku, a o we e, ni opo igba okan ninu awon ebi re, a o si we e ni aso fufun, a o si sin pelu adura kekere bi o ba seese ni ojo kanna ti o ku. Awon Musulumi ri eyi gegebi okan ninu awon ise ikehin ti awon le se fun awon ebi won, ati anfani fun won lati ronu nipa igbe aye ti won naa ninu aye yi. Annabi ko wa wipe awon nkan meta wa ti o le maa ran eniyan lowo lehin iku; awon itore aanu ti o ti se, imo ti o ti ko ati adura ti a se fun lati owo omo olododo.


Kini Islam so nipa ogun?

Gegebi esin Kristiani, Islam fi aye gba jija lati dabo bo ara eni, dabo bo esin, tabi fun awon ti ati fi ipa le kuro ninu ile won. Islam fi ofin nla lele nipa ogun jija lara eyi ti ko fi aye gba pipa awon ara ilu ti ki I se jagunjagun, ati lati ma se pa awon eso, ohun ogbin tabi awon ohun osin lara. Gegebi awon Musulumi ti mo, aisododo yi o gba aye kan ti awon eniyan rere ko ba setan lati fi emi won jin lati ja fun ododo. Kuran so wipe:

Ki e si maa ba (won ja) l’oju ona Olohun awon eniti o nba yin ja, sugbon ki e mase rekoja ala, dajudaju Olohun ko feran awon ti o nreko ja ala.

(Kuran 2:190)

Bi nwon ba te si alaafia, ki ire na te si I ati ki o si fi ara ti Olohun. Dajudaju On ni Olugboro, Onimimo.

(Kuran 8:61)

Ogun je ohun ti a ko gbodo ku giri si, o si gbodo tele ilana ti a ti ko sile ninu ofin mimo. Oro yi Jihadi tumo si ‘itiraka’, awon Musulumi si gbagbo pe orisi Jihadi meji ni o wa. ‘Jihadi’ keji ni itiraka atinu wa lati doju ija ko gbogbo iwa buruku inu eniyan, lati le ni ifokanbale to peye.


Nipa ounje nko?

Bo tile je wipe o rorun ju ofin ounje ti awon Ju ati awon Kristisni isaju ntele, ofin ounje ti awon Musulumi ntele wipe won ko gbodo je eran elede tabi otikoti to le pani. Annabi ko wa wipe ‘ago ara re ni ase lori re’, ati jije ounje ti o peye ati gbigbe igbe aye ti onilera je awon ohun ti o je ojuse wa ninu esin.

Annabi wipe:

‘Beere lowo Olohun fun aridaju [igbagbo] ati ise-rere; nitori lehin aridaju, ko si eni ti o tun ri ebun kan gba to ju ilera lo!’


Bawo ni Islam se fi idi eto omo eniyan mule?

Ko si ifi agbara mu ni ninu esin. Ona otito ti farahan kuro ninu ona isina.

(Kuran 2:256)

Aye ati awon ohun ini gbogbo awon ara orile-ede Islam ni a ka si mimo yala onitohun je Musulumi tabi rara.

Eleyameya je ohun ti o se ajeji si awon Musulumi, nitori Kuran so nipa idogba awon eniyan lona wonyi:

Eyin eniyan, dajudaju A da nyin lati ara okunrin ati obinrin, A si se nyin ni orile ede ati iran-iran ki e le ba maa mo ara nyin.Dajudaju eniti o ni ola ju lodo Olohun ninu yin ni eniti o paiya (Re) ju . Dajudaju Olohun ni Onimimo Alamotan.

(Kuran 49:13)

Islam ni Orile-ede Amerika

Mosalasi ni New Mexico, U.S.A.

O soro pupo lati soro nipa akojopo gbogbo awon Musulumi ni orile-ede Amerika: awon ayipada, awon arinwole, osise ile-ise, onisegun; gbogbo won nsa ipa won fun ojo ola Amerika. Awujo ti o gboro yi wa ni isokan nipa igbagbo won, ti o seese nipa se awon netiwoki egbegberun mosalasi kaakiri orile-ede.

Awon Musulumi wa lara awon ti o koko de Ariwa Amerika. Lehin ogorun odun mejidinlogun, opolopo egberun won wa ti won nsise gegebi eru lori awon oko nla. Awon awujo isaju wonyi lehin opo odun ti won ko si pelu awon ebi ati asa won, won bere si ni so idanimo won nu. Loni, opolopo awon Musulumi ni Amerika to je omo Afirika lo nsa ipa ribiribi laarin awujo awon Musulumi.

Ibi Asa Islam, Washington DC.

Ni ogorun odun mokandinlogun, opolopo awon Musulumi lati ile Arabu wole wa, won si ngbe ni awon ilu ti o ni ile ise nla, won si njosin ni awon yara ti won san wo gba. Ni ibeere egbewa odun, opolopo ogorun awon Musulumi ni o wole wa lati Ila orun Europe: mosalasi Albania akoko ni a si ni Maine ni 1915; opo si tele, awujo awon Musulumi kan lati Poland si mosalasi kan ni Brooklyn ni 1928.

Ni 1947, a seda Ibi Asa Islamti Washington ni igba ijoba Aare Truman, opolopo awon egbe kaakiri orile-ede ni a si da sile ni awon odun 1950s. Ni awon akoko yi bakanna ni a ni awon egbe titun kan ti a da sile ni ilana Islam. Ni aipe yi, opolopo awon egbe yi ni o ti darapo mo Islam. Loni, a ni bi egberun lona egberun marun Musulumi ni orile-ede Amerika.


Aye Awon Musulumi

Agbala Mosalasi nla,
Heart, Afghanistan.

Awon Musulumi ni ile aye to egberun lona egberun lona egberun kan eniyan. Ida ogbon ninu ogorun awon wonyi ngbe ni iha-kontineti India, ida ogun ninu ogorun ngbe ni iha isale Sahara Afirika, ida metadinlogun ninu ogorun ni Ila orun Gusu Asia, ida mejidinlogun ninu ogorun ngbe ni ile Arabu, ida kan ninu mewa wa ni Soviet Union ati China. Turkey, Iran ati Afghanistan je ida kan ninu mewa awon eniyan ti ki I se Arabu ti won ngbe ni arin gbugbu Ila orun. Botileje wipe awon awujo Musulumi kekeke wa kaakiri gbogbo ibi, pelu Latin Amerika ati Australia, won po ni Soviet Union, India, ati arin gbugbu Afirika. Egberun lona egberun marun awon Musulumi ni o wa ni Orile-ede Amerika.

Eyin eniyan, dajudaju A da nyin lati ara okunrin ati obinrin, A si se nyin ni orile ede ati iran-iran ki e le ba maa mo ara nyin.Dajudaju eniti o ni ola ju lodo Olohun ninu yin ni eniti o paiya (Re) ju . Dajudaju Olohun ni Onimimo Alamotan.

(Kuran Quran 49:13)
Mosalasi Unifasiti ti Al Azhar – ibi ikeko lati odun 969 AD.
Irani | Mali
Mosalasi Al-Khulafa, Al Rashidin,
Asmara, Eritrea.
Shibam, Hadramout, Yemen
(Ile Oba-binrin Sheiba.)