Ere idi Iwalaye

O je ohun iwuri fun mi lati ni anfani yi lati ba yin soro ni ibi yi. Mo si fe so fun yin pe eyi ki I se idanileko… Mi o ro pe mo wa ni igbaradi lati dan’leko. Sugbon o je bi…amoran fun ara mi paapaa. Nitori mo ri ara mi gegebi ookan ninu awon ti o joko si ori awon aga wonyi ni iwaju mi. Ni iwon ojo die seyin, ni iwon odun die seyin, ni iwon igba die seyin – mo joko ni ibi kan na nibi ti e wa yi, orile ede yi o wu tie ti le ti wa – ko ni fi se. Mo je eniyan ti ko mo nkankan nipa Islam. Ati ni igba yi, mo je enikan ti ko ni oye… sere idi iwalaye!

Nitori idi eyi, mo bebe pe ki e ri ohun ti mo n so loni gegebi alaye ati imoran – ki si I se bi idanileko. Imo naa ti mo fe pin pelu yin, o le da bi eni pe o fe po die. Ni gba ti e ba ye idiwon agbara opolo eniyan wo ati iwon oye imo ti o le fi pamo – e o ri wipe iwonba alaye ti mo fe se loni, ko le d’erupa yin.

Ojuse mi ni lati soro nipa awon koko ijiroro wa toni – ki ni ere idi iwalaye wa? Ati pelu ki n bere ibeere yi – “Ki llo mo nipa esin Islam?” Eyi ni ni wipe – kini ohun ti o mo ni pato nipa Islam? Ki I se ohun ti o ti gbo nipa Islam; Ki I se ohun ti o ti ri gegebi iwa awon Musulumi kan, sugbon – ki ni o mo nipa Islam?

O je ohun iwuri fun mi lati ni anfani yi, mo si fe beere nipa siso wipe gbogbo yin pata ni e ni ojuse kanna… Ojuse yi si nip e ki e f’eti sile tabi ka a – pelu okan ti a si sile.

Ninu aye yi ti o kun fun ojusaju ati orisirisi asa, o je ohun ti o soro lati ri eniyan ti o le ya akoko soto lati ronu. Lati ro arojinle nipa iwalaye, lati gbiyanju lati wadi otito nipa aye yi ati ere idi toto ti iwalaye wa. Sugbon o se ni laanu wipe ni igba ti e ba bi awon eniyan leere ibeere yi – “Kini ere idi iwalaye wa?” eyi ti o je ibeereti o se koko ti o si se pataki julo, won ki yi o so fun o ohun ti won ti ri tabi ro. Ni opo igba, o daju pe won yi o so fun o ohun ti elomiran ti so… Tabi ohun ti awon miran nro. Ohun ti baba mi so pe ere idi iwalaye je, ohun ti alufa ijo mi so pe ere idi iwalaye je, ohun ti oluko mi ni ile-iwe so, ohun ti ore mi so.

Ti mo ba bere lowo enikeni nipa ere idi ounje jije, “Ki ni idi ti a fi njeun?” Opolopo eniyan yi o dahun, ni ona kan tabi omiran, “O wa fun eto ijeemu ara!” Nitori ounje mu wa wa laaye… Ti mo ba beere lowo enikeni idi ti won fi n sise? Won yi o wipe, nitori o se Pataki lati le ran ara won lowo ati pese fun awon ebi won. Ti mo ba beere lowo enikeni idi ti won fi n sun, idi ti won fi n we, idi ti won fi n w’oso ati bebelo, won yi o dahun – “Awon nkan wonyi je ohun ti o se Pataki fun gbogbo eniyan.” A le tesiwaju bayi nipa bi beere ibeere to to ogorun, a o gbo idahun kan na tabi iru kan na lati odo enikeni, ni ede yi o wu, nibikibi ni aye yi! “Ki lo de, ni gba ti a ba bere ibeere yi, ‘Kini ere idi iwalaye wa?’, ti a ma ri orisirisi idahun?” Idi ni wipe ona awon eniyan ruju, won ko mo. Won wa ninu okunkun. Sugbon yala ki won so wipe “Emi ko mo,” won a kan dahun awon idahun ti o ti a ti fi si opolo won.

E je ki a ro nipa eyi. Nje ere idi iwalaye wa ninu aye yi kan ni lati jeun, sun, w’oso, se ise, ko awon ohun ini jo ki a si gbadun ara wa? Nje eyi ni ere idi wa? Kini ere idi ti a fi bi wa? Kini idi iwalaye wa, kini ogbon to wa leyin dida ti a da eniyan ati ile aye nla yi? E ro nipa ibeere yi!

Awon kan n jiyan pe ko si idaniloju pe se ni a da wa, pe ko si eri pe Olorun wa, pe ko si idaniloju pe ada ile aye yi nipa imo Olorun Kankan. Awon eniyan wa ti won gbagbo bayi – won si ma n so wipe ile aye kan wa be ni. Iron la dun, ile aye yi pelu ohun gbogbo ninu re si waye bee. Won si njiyan pe iwalaye wa ko ni idi Kankan ati pe ko si ohun kohun ti a le fi fi idi re mule yala nipa ero wa tabi imo ijinle sayensi pe Olorun wa, tabi ere idi, tabi imo Kankan nipa ile aye yi.

Nibi n o ka awon ese Kankan ninu Kurani ti o so nipa koko yi.

“Dajudaju ninu eda orun ati ile ati titele (ara won) oru ati osan, ami mbe fun oni-lakaye. Awon eni ti nranti ni iduro ati ni ijoko ati ni idubule won, tin won nronu nipa iseda orun ati ile: (ti nwon wipe) Oluwa wa! Iwo ko da (gbogbo) eyi lasan! Ogo ni fun O! nitorina gba wa la kuro ni bi ya ina.”

[Kuran 3: 190-191]

Ni awon ese ti a ka loke yi, Allah so fun yeke, ni akoko nipa fi fa okan wa si dida wa gegebi eniyan. Orisi eya eniyan ati orisi iwa awon eniyan. O fa okan wa si awon orun. Iyipada larin ojo ati oru. Ofurufu, awon irawo, awosanmo… O si so fun wa wipe oun ko da awon nkan wonyi lai nidi! Nitori ni igba ti o ba wo igbekale won, wa a ri wipe igbekale naa dara o si gun rege o si ju isiro ati imo wa lo – ko le je lasan. Ko kan le wa lasan.

Fun apeere, ti o ba mu okuta mewa ti o si ko onka si ori won lati okan de ori mewa. Ti gbogbo won si je orisi awo ti o yato sira won. Ti o ba ko won si inu apo ti o si mi apo naa papo. Ki o wa di oju re, ki o fi owo si inu apo naa, “ki o wa maa mu awon okuta naa jade leyo Kankan ni sise ntele lati ori akoko titi de ori ikewa.” Bawo ni o sese si fun o lati mu awon okuta naa jade ni sise ntele? Nje o mo bi o seese si? Milionu mefa si okan! Nitorina, kini anfaniboya o seese pe orun ati aye yi kan waye be, ki won si wa ni pipe bi won se wayi? Kini aye fun eyi?

Eyin olugbo ati alejo mi owon – a ni lati bere ibeere kan si l’owo ara wa… Ni igba ti o ba ri afara, ile, tabi oko – dajudaju wa ro nipa eni tabi ile-ise to se e. Ni igba ti o ba ri oko ofurufu, roketi, satelaiti, tabi oko oju omi nla – wa tun ro bakanna nipa bi oko naa se tobi to. Nigba ti o ba ri ile ohun elo iparun, ibudoko oko ofurufu pelu gbogbo awon ohun elo ti o nbe nibe, bakanna ti iwo ba ro nipa awon ohun meremere ni ihin, ni orile-ede yi – yi o je ohun iwuri fun o awon imo ero ijinle ti a ti fi se awon nkan wonyi.

Be, awon wonyi je awon nkan ti a aseda lati owo awon omo eniyan. Bawo ni ara eniyan pelu gbogbo eya re? Ro ni pa re! Ro nipa opolo— bi o ti n ronu, bi o ti n sise, fi alaye pamo, se iyato laarin alaye laarin iseju aaya! Opolo ma n se awon nkan wonyi ni gbogbo igba. Ro ni pa opolo fun igba die. Eyi ni opolo to se awon oko, oko oju omi, oko oju ofurufu ati bebelo. Ro nipa opolo ati eni ti o se. Ro ni pa okan, bi o ti n sise pinpin eje lai simi fun ogota tabi adorin odun – ni pinpin eje kaakiri gbogbo ara, ati si se ise ni dede ti de opin ile aye eni naa. Ro ni pa re! Ro ni pa awon kidirin – irufe ise ti won nse? Eya ara ti o n se afomo gbogbo ago ara, ti o si mo juto oye idoti tin be ninu ara. O ma nse eleyi fun ara re. Ro ni pa awon oju re – ayaworan ara ti o n wo, ti o nmu ti o si n se amulo awon awo orisirisi fun ara re. Eyi ti o gba itana fun ara re. Ro nipa re – tani eni o da iwonyi? Tani o pete re? Tani o pinle re? Tani on se abojuto re? Awon eniyan fun ara won bi? Rara

Bawo ni agbaye yi? Ro ni pa eyi. Ile aye yi je okan ninu awon isogbe-orun ninu eto oorun wa. Eto oorun wa si je okan ninu awon eto ti o wa ni Milky way. Milky Way si je okan ninu awon akojo irawo ni galasi. Egberun lona egberun galasi ni o si wa. Ro nipa eyi. Gbogbo won ni won si wa leto leto. Won pe perepere. Won ko kolu ara won. Se awon eniyan ni won se eyi? Se awon eniyan ni o n mu oju to won? Rara, ki se awon eniyan.

Ro nipa awon okun nla, awon eja, awon kokoro, awon eye, awon ohun ogbin, awon kokoro kekeke, awon kemika ti a ko I ti se awari ati ti a ko tile le se awari won pelu imo ijinle wa. Bee, gbogbo won ni won ni ofin ti won n tele. Nje gbogbo amusisepo yi, eto yi, iyato yi, itoju yi, ati ailonka yi – nje eyi waye lasan? Ati pe, se awon nkan wonyi n sise ni pipe lasan? Se won si n seda ara won lasan? Rara, ki I se be?

Lati ro bayi yi o je iwa ope ati ti omugo. Bi o ti wu kori, ona kana yi o wu ti awon nkan wonyi gba waye koja oye ati agbara eniyan. Gbogbo wa pata la gba eyi. Eni ti ope ati iyin to si ni alagbara julo – Olorun. Olorun ni o da gbogbo nkan wonyi, O n naa ni o si n se abojuto won. Nitorina, Olorun nikan ni gbogbo iyin ati ogo ye fun.

Ti mo ba fun enikankan yin ni ogorun dola, lai ni di, wipe e kan wa si ihin lasan, o kere ju e o tile so wipe “O seun.” Sugbon, wo oju re, awon kidirin re, opolo re, emi re, imi inu re, awon omo re? Ro nipa wonyi. Ta lo fun o ni iwonyi? Nje O ye fun iyi ati ope re? Nje ko ye lati gba ijosin ati idanimo re? Arakunrin mi ati Arbinrin mi, ni soki, eyi ni ere idi iwalaye wa.

Allah so ninu Kurani:

“Atipe Emi ko se eda alijonu ati enia lasan ayafi ki nwon le ma sin Mi.”

(Kuran 51: 56)

Eyi ni ohun ti Olorun Atobiju so. Nitorina ere idi wa ni aye yi ni lati da Aseda wa mo ati lati fi ope fun Aseda wa. Lati josin fun Aseda wa. Lati yonda ara wa fun Aseda wa. Lati pa ofin Re mo ti o ti gbekale fun wa. Ni soki, o tumo si ijosin. Eyi ni ere idi iwalaye wa. Ohunkohun ti a ba si se ni ipase ijosin wa—ni jije, ni mimu, ni wi wo aso, ni ise sise, ni igbadun larin iwalaye ati ipo oku—gbogbo wonyi kan je afikun. A da wa fun ijosin – eyi ni ere idi iwalaye wa. Mo gbagbo pe awon onimo ijinle ati elero nla gan yi o gba ere idi yi. Won le ni ero miran ninu won o, nkan miran niyen, sugbon eyi je ohun ti won ni lati yanju laarin awon ati Olorun.

Nisiyi, eje ki a wo apa keji koko yi. Kini ohun ti o mo nipa Islam? Ki I se ohun ti o ti gbo nipa Islam. Ki I se ohun ti o ti ri ninu iwa awon Musulumi, nitori iyato wa laarin Islam ati awon Musulumi. Gegebi iyato se wa laarin ki eyan je okunrin ati ki o je baba. Okunrin ti o ni omo – oun ni baba, sugbon jije baba mu ojuse lowo. Ti okunrin ko ba se awon ojuse yii, ko ki n se baba rere. Islam je ilana ati eto. Ti Musulumi kan ko ba tele awon liana yi, ki I se Musulumi rere. Nitorina, e o le fi Islam we awon Musulumi.

A maa ngbo awon oro yi ‘Islam’ ati ’awon Musulumi’ ni opo igba. A si ma n ka nipa Islam ati awon Musulumi ninu awon iwe iroyin, iwe kika ti ile eko giga ati ile eko giga julo. A maa nka a si ma nri opolopo awon asiko ati alaye asinilona lori awon ero agbohunsafefe. Mo si ni lati so wipe awon alaye ba wonyi ni igba miran ti wa laye lati owo awon Musulumi fun ara won. Sibe, okan ninu eniyan marun ninu egberun lona egberun lona egberun marun eniyan je Musulumi! E yi je onka ti e le se iwadi re ninu awon iwe imo ofe, tabi almanac, tabi awon orison miran ti o ba wu yin lati ye wo. Ba wo lo se je to ba je pe okan ninu eniyan marun nile aye je Musulumi ti a ko fi mo nkankan nipa Islam? Awon eridaju nipa Islam. Ti mo ba so fun o wipe okan ninu eniyan marun ni ile aye yi wa lati orile ede China, eyi ti o je ododo – eniyan egberun lona egberun lona egberun kan nile aye yi ni o wa lati orile ede China, eniyan eyokan ninu marun ninu aye yi je omo China! A si mo nipa itan, oselu, eto oro aje ti orile ede China ati awon omo China! Ki lode ti a ko wa mo nipa Islam?

Kini ohun ti o so opolopo orile ede ni gbogbo agbaye yi papo ni isokan? Ki ni o ma mu ki arakunrin kan tabi arabinrin kan lati orile ede Yemen je arakunrin mi tabi arabinrin mi, mo si je omo America. Ti o ma mu ki arakunrin yi lati Eritrea je arakunrin mi. Ti o si mu arakunrin miran lati Indonesia je arakunrin mi. Ati arakunrin lati ile Afirika je arakunrin mi. Ati omiran lati Thailand, ati omiran lati Itali, Greece, Polandi, Colombia, Bolivia, Costa Rica, China, lati Spaini, lati Russia ati bebelo. Kini ohun to mu won je arakunrin tabi arabinrin mi!? Awa ti a ni eya ti o yato, ede ti o yato ati ipinlese ti o yato? Kini ohun ti o wa ninu Islam ti o so wa po di okan soso? Kini awon eya ti o se koko ninu ona ti ko ye opolopo yi sugbon ti opolopo awon eniyan aye yi n tele?

Maa gbiyanju lati fun yin ni awon eri Kankan. Sugbon ni afikun si eyi, gegebi mo ti wi fun yin tele. O se pataki fun yin lati si okan yin sile – nitori, ti mo ba do ju ife kodo ti mo da omi le nko le ni ife to kun fun omi. O ni lati si oju soke. Eri lasan ko le mu oye wa, sugbon akojo eri, igbalaye ati isi okan sile lati gba otito ni igba ti eniyan ba gbo o.

Oro na ‘Islam’ tumo si iyanda, ijowo ara eni, ati igboran. Iyanda, ijowo ara eni ati igboran si ofin Olorun Atobiju. O le so wipe ‘Allah.’ O le so wipe ‘Aseda.’ O le so wipe ‘Olorun Atobiju,’ ‘Alagbara julo,’ gbogbo wonyi ni oruko re.

Awon Musulumi ma nlo oro larubawa Allah fun Olorun, nitori ni ede larubawa, ko si oro miran ti a le lo. A ko le lo oro naa Allah fun ohunkohun ti a da. Awon oro miran ti a ma n lo fun Atobiju a ma tun nlo fun awon ohun ti a da. Fun apeere, “dola atobiju.” “Wo bi mo ti feran aya mi to, o le nle!” Tabi, “Oun lo gaju.” Rara, rara, rara… Eni ti o da gbogbo awon nkan wonyi ti a ti da’ruko yi nikan ni o le je oruko naa ‘Allah’. Nitorina, lati isinyi lo N o maa lo oruko naa ‘Allah’, e si ti mo eni ti mo n so nipa re.

Oro naa ‘Islam’ jeyo lati idi oro ‘Salama’ – ti o tumo si lati wa ni alaafia. Nitorina, Musulumi je eniyan ti o yanda ara re, ti o jowo ara re, ati ti o si gboran si ofin Olorun Atobiju. Ati ni pase ijowo ara eni yi yi o gba alaafia ati ifokanbale fun ara re. A le ripe nipa alaye yi, oro larubawa yi ‘Islam’ na tun se apejuwe awon iwa ati ihu iwasi awon anabi ati ojise Olorun Atobiju … Gbogbo won pelu Adamo, Noa, Ibrahim, Musa, Dauda, Sulaimon, Isiaka, Ismoila, Yakubu, Yohanu Onitebomi, Suleiman, Isa omo Maria, ati Muhamadu (ki Alaafia Allah wa lori gbogbo won.) Gbogbo awon okunrin wonyi, awon anabi ati ojise yi lati odo Olorun Atobiju kanna, pelu ise iranse kanna, pelu igbekale kanna, won si so nkan kanna – gboran si Olorun! E josin si Olorun Atobiju ki e si mu ere idi iwalaye yi se ati ki e se rere, a o si fun yin ni aye miran. Eyi nikan ni won so! Ma se b pe o ju eyi lo! Eyi nikan ni won so, edekede yi o wu ati akoko yi owu, tabi eni ti a ran won si – Eyi nikan ni won so.

Ti e ba ka iwe mimo pelu ifarabale, lai fi itumo ti ara re si tabi afikun lati odo elomiran tabi ero elomiran – iwo yi o ri wipe eyi ni ise iranse ti gbogbo awon anabi yi mu wa ti won si jeri ara won. Ko si eyikeyi ninu awon anabi yi ti o wipe, “Emi ni Olorun – e maa josin fun mi.” Iwo ki yi o ri eyi ninu eyikeyi iwe mimo ti o wa ni owo re – yala Bibeli, tabi Torah, tabi Majemu Titun, tabi Orin Dafidi – iwo ki yi o ri ninu iwe Kankan.Iwo ki yi o ri ninu eko anabi Kankan. Lo si ile ni asale yi ki o si ye gbogbo oju iwe Bibeli re wo, mo seleri fun O – iwo ki yi o ri eyokan. Nibikibi! Nitorina, nibo ni eyi ti wa? Eyi je ohun ti o gbodo se awari re.

A le ri lati inu alaye yi pe, oro larubawa yi se apejuwe gbogbo ohun ti awon anabi se. gbogbo won wa won si jowo ara won fun Olorun; won pe awon eniyan wa si odo Olorun; Won si so fun awon eniyan lati wu iwa ododo. Awon ofin mewa ti Musa – kini eyi? Eko Ibrahim – kini eyi? Orin Dafidi – kini eyi? Awon owe Sulaimon – kini o so? Ihinrere Jesu Kristi – kini O so? Kini Johanu Onitebomi so? Kini Isiaka ati Ismoila so? Kini Muhamadu so? Ko ju eyi lo!

“A ko pa won lase ju pe kin won josin fun Olohun lo, ki nwon fo esin mo fun U, kin won se dede ki nwon ma gbe irun duro, kin won ma yan saka atipe eyi ni esin ti o duro dede.”

[Kuran 98:5]

Eyi ni ohun ti Allah wi. Won ko si pase kan ju pe ki a josin fun Allah, ka fi okan si odo Re.

Eyi si ni ona na, eyi ni ise iranse naa tooto. Bakanna, o dara ki a ri awon anabi ati awon ojise gegebi Musulumi, nitori ‘Musulumi’ je kini? Ma ro nipa oro larubawa yi, ma ro nipa bi a ti ma npe won- ma ro nipa Moka tabi Saudi Arabia, tabi Egypiti. Rara! Ro nipa ohun ti oro yi ‘Musulumi’ tumo si. ‘Eni ti o yanda ara re fun Olorun Atobiju, ti o si n gboran si awon ofin Olorun Atobiju,’ ni idi eyi yala lona ayebaye tabi ni ti ede – ohunkohun ti o ba yonda ara re fun Olorun Atobiju je Musulumi!

Nitorina, ti omo ba jade ninu iya re ni akoko ti Olorun ti yan – kini eyi? O je Musulumi. Ni igba ti oorun ba n yipo – kini eyi? O je Musulumi! Ni igba ti osupa ba nyipo oorun – kini eyi? O je Musulumi! Ofin Ile – kini eyi? O je ofin Musulumi! Ohunkohun ti o ba jowo ara re fun Olorun je Musulumi! Nitorina, ni igba ti a ba finufedo gboran si Olorun a je Musulumi! Jesu Kristi je Musulumi. Iya re je Musulumi. Ibrahimu je Musulumi. Mose je Musulumi. Gbogbo awon anabi ni won je Musulumi! Sugbon won wa si odo awon eniyan won, won si so orisirisi ede. Anabi Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) so ede larubawa. Ati nitorina, ni ede Larubawa enikeni ti o ba jowo ara re ti o si yonda ara re je Musulumi. Gbogbo anabi ati ojise Olorun Atobiju mu ise iranse kanna wa—‘E josin fun Olorun Atobiju ki e si fi okan s’odo Re.’ Bi a ti n ye ise iranse ikankan awon anabi ti o gbajumo yi wo, a le fi idi eyi mule.

Ni igba ti ede aiy’ede ba wa, itenumo eke, adapo iro ati asodun, fifi itumo ti ara eni si akosile awon onkowe, onkotan ati eni kokan ni o ma n se okufa eyi. Fun apeere, eje ki n fi nkankan han yin eyi ti e ti le yewo tele. Gegebi Kristiani, mo ti yewo tele ki n to di Musulumi ati pe… ko si ye mi. Ki lo de to je wipe ni gbogbo Majemu Lailai, Olorun je okan soso—Oluwa ati Oba gbogbo agbaye. Eyi si ni ofin akoko ti a fifun Mose, ko je ki enikeni josin fun ere gbigbe kan; tabi fi ori bale fun ohunkohun ni awon Orun, tabi ni Aye, tabi ninu okun – Ko gba eyi laaye. Gbogbo awon anabi so wipe Olorun kan soso ni o wa. Ni gbogbo Majemu Lailai a ntun eyi so lai mo oye igba. Ni igba to ya, lojiji a ni orisi eri merin – ihinrere merin ti a pe ni Matiu, Maku, Luku ati Johanu. Matiu wo? Maku wo? Luku wo? Johanu wo? Ihinrere merin ototo ti a ko ni iwon odun meji-din-l’adota si ara won. Ko si si eyikeyi ninu awon okunrin yi ti won ko fo wo sowopo pelu ara won ti o so oruko baba won. Ti mo ba fun o ni iwe igbowo jade lati banki lati san owo osun re ti mo si ko oruko mi lai fi oruko baba mi si nje iwo yi o gba ni owo mi? Rara, iwo ki yi o gba a… Ti olopa ba da o duro ti o si beere fun kaadi idanimo re, ti o si je wipe oruko re akoko nikan ni o wa lori re, nje eyi yi o je itewogba lodo re? Nje o le gba iwe irina oke okun pelu oruko re akoko nikan? Nje baba ati iya re fun o ni oruko eyokan? Nibo ni itan awon eniyan ni oruko eyokan se je ohun itewogba fun akosile, nibo? Ko si! Ayafi ninu Majemu Titun.

Bawo ni o se le gbe igbagbo re si ori Ihinrere merin ti a ko lati owo awon okunrin merin ti won ko mo oruka baba won? Leyin eyi, a tun ni awon iwe meedogun si ti a ko lati owo okunrin kan ti o je eni eke ti o n pa awon Kristiani, ti o pon awon kristiani loju, ti o si wa so wipe oun ri Jesu ni inu iran. A si yan gegebi Aposteli fun Jesu. Ti mo ba so fun o pe Hitler lehin ti o pa awon Ju wa so wipe oun fe di eni igbala. Pe o si wa pade Mose tabi Jesu ni ona o si wa di Ju. O si ko iwe meedogun o si fi won kun Torah – nje awon Ju yi o gba eyi? Rara, iwo ki yi o gba eyi. Nitorina, bawo ni iwe merin ti a ko lati owo awon okunrin merin ti won ko mo oruko baba won ati iwe meedogun miran ti a ko lati owo okunrin miran—eyi si ni igba akoko ti a o pe Olorun ni eniyan, igba akoko ti a o so wipe meta ni Olorun, ati igba akoko ti a fun Olorun ni omokunrin— bawo ni awon Kristiani se gba eyi? Bawo? Ro nipa eyi! A ko ni j’iyan nipa koko yi. N o kan fun yin ni nkan lati ronu le lori.

Iwas’aye Anabi Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) ko mu esin titun tabi igbe aye titun wa saye bi awon miran se nso. Lodi si eyi, Anabi (Ki Alaafia Wa Pelu Re) fi idi ise iranse gbogbo awon anabi ati ojise to ti siwaju mule. Yala nipa ihuwasi re tabi nipa awon ifihan ti o gba lati odo Olorun Oba. Iwe Mimo ti Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) mu wa ni a npe ni Kuran. O tumo si ‘eyi ti a ka.’ Nitori Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) ko ko Kuran. Oun ko lo ko Kuran. Enikeni ko wa lati ba ko Kuran. Ko si si eni ti o fi owo sowopo pelu re lori eyi. Malaika Jubril ni o ka awon oro naa fun! Olorun Oba si je ki okan re gba awon oro naa. Okan Anabi (Ki Alaafia Wa Pelu Re) gba ifihan yi a si ni Kuran ti a ti pamo lati opolopo odun lai yi pada. Nje iwe miran wa ninu aye yi ti o mo ti a ti pamo gegebi ati fihan laisi iyipada Kankan? Ko si iwe… Kuran nikan.

Ma kan gba oro mi gbo, lo si ile ikawe ki o si ye ohun ti a ko sile ninu iwe imo ofe ti Britanika tabi iwe imo ofe ti agbaye tabi iwe imo ofe ti America, tabi eyikeyi iwe imo ofe ni agbaye ti a ko ko lati owo awon Musulumi. Ka ohun ti o ko nipa Islam, kuran, ati Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re). Ka ohun ti awon ti ki I se Musulumi ko nipa kuran, Islam, ati Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re). Ni igba na ni iwo yi o gbagbo pe ohun ti mo nso wa ni ki ko sile ka ri aye! Pe Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) ni eniyan ti o ni iyi julo ni itan gbogbo agbye. Ka ohun ti won ko. Pe Kuran je iwe ti o ya ni lenu ju ninu itan agbaye! Ka ohun ti wwon so. Pe igbe aye Islam je eyi ti o kun fun emi!… Ko si ti I yi pada.

Iwe mimo ti Muhamadu (PBUH) gba ni a npe ni ‘Kuran.’ Ikokan ninu awon anabi ati ojise ni o si gba iwe mimo yi. Ninu Kurani, awon anabi yi, iwe mimo won, itan won, ati opo ise ti a fun won ni a ko sile ni kikun. Nje Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) pade won, ba won soro, ba won jeun, ati fo wo so wo po pelu won lati ko itan igbesi aye won? Rara, ko ba won pade ri. Ninu Kuran, Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) ni a mo si ojise Olorun ati akotan awon anabi isaju—eyi ni ti I se ojuse re to gaju gegebi omo eniyan.

“Muhamadu ki ise baba enikankan ninu awon okunrin nyin, sugbon (o je) Ojise Olohun ati ipekun awon annabi. Olohun je Oni-mimo nipa gbogbo nkan.”

[Kuran 33:40]

Awon Musulumi ki I josin fun Muhamadu. A ki I se omo lehin ‘Muhammadu.’ A ko ni eto lati pa oruko Muhamadu da ki a wipe a je omo lehin Muhamadu. Awon ti o tele musa ki I se omo lehin Musa. Rara, awon ti o tele Yakubu ki ise omo lehin Yakubu. Tabi awon ti o tele Ibrahim ki I se omo lehin Ibrahim Tabi omolehin Dafidi. …Rara, rara, rara. Nitori na, bawo ni awon eniyan se n pe ara won ni ‘Kristiani?’ Kristi ko pe ara re ni ‘Kristiani,’ ki lo wa de ti awon eniyan n pe ara won ni ‘Kristiani?’

Jesu Kristi (PBUH) so wipe ohunkohun ti oun ba gba lodo Olorun je oro Olorun, ati ohun ti oun ba gbo ni oun n so! Ohun si ni oun nse! Nitorina, ki lode ti awon eniyan npe ara won ni ‘Kristiani?’ A ni lati wu iwa bi Kristi! Bawo ni Kristi ti ri? O je eru Olorun; nitorina a gbodo je eru Olorun.

Gegebi iwe mimo ati ifihan atokewa ti o kehin, kurani so oro yi pelu idaniloju wipe,

“Loni yi Mo se esin yin ni pipe fun nyin ati pe Mo se asepe idera Mi le nyin lori ati pe Mo yonu si Islam ni esin fun nyin.”

[Kuran 5:3]

Nitorina oro naa ‘islam’ wa lati ipa se kuran. Nitori ti a ba ti ko ile tan, aa pe ni ‘ile.’ Ni igba ti oko ba si wa ni ile ise ti a ti n se, a ko I ti le pe ni oko,o si wa lenu sise! Ni igba ti a ba pari re, ti a ti ye wo ti a ti waa wo – o ti di ‘oko.’ NI igba ti Islam pari gegebi ifihan, gegebi iwe, bi apeere lati owo Anabi Muhamadu (PBUH), o wa di ‘Islam.’ O di liana igbe aye.

Nitorina, oro naa ni o je titun ki I se iwa … ki I se anabi… ki I se liana lati odo Olorun… ki I se Olorun titun…ki I se ifihan titun… sugbon oruko titun nikan, Islam. Bi mo si ti wi saaju, tani gbogbo awon anabi wonyi? Gbogbo won jee Musulumi. Ohun miran ti e tun gbodo fi sokan ni wipe Muhamadu (PBUH), yato si awon ti won ti wa siwaju re – ko wa si odo awon Arabu tabi awon eniyan re nikan. Rara… Nitorina, Islam ki I se esin awon Arabu. Bo ti le je wipe Anabi Muhamadu, omo Abdulahi, a bi ni Moka, ilu ti o wa ni agbegbe Arabia, o si je Arabu, ko mu Islam wa fun awon arabu nikan. O mu Islam wa fun gbogbo eniyan.

Bo tile je wipe, a se afihan Kuran ni ede larubawa, ko tumo si wipe ise iranse Muhamadu wa fun awon ara Arabu nikan. Nunui Kuran mimo, Allah so wipe,

“Atipe Awa ko wule ran o nise ayafi ki o le je ike fun gbogbo aiye.”

[Kuran 21:107]

Anabi Muhamadu (Ki Alaafia Wa Pelu Re) so wipe: Gbogbo eda eniyan wa lati odo Adamo ati Efa, ara Arabu ko ni ase lori eni ti ki I se Arabu; beeni alawo funfun ko ni ase lori alawo dudu yala alawo dudu lori alawo funfun bikose nipa iwa pipe ati ise rere.

Ni idi eyi, Muhamadu (PBUH) je akotan ati ade ori gbogbo awon anabi ati ojuse ti o ti siwaju re. Opolopo awon eniyan—won ko mo nipa alaye yi.

Nitoripe mo n toka si Kurani lati se eri fun oro mi, maa se alaye die nipa ipinlese Kurani fun ara re. Ni akoko, Kuran so wipe ere ise ifihan ni ohun je. Eyi ni wipe, a ran-an sokale wa lati odo Olorun Atobiju si muhamadu fun imisi.

Allah so wipe,

“Atipe ki nso oro ife-inu.”

“On ko je kinikan bikose ise ti a ran (si I).”

[Kuran 53:3-4]

Muhamadu ko soro nipa ara re, ero re, ife re, tabi edun re. Sugbon, eyi je ifihan ti a fi han-an! Eyi je oro Allah. Nitorina, ti mo ba fe je ki e gba otito Kurani gbo, mo ni lati je ki e mo – ni akoko, pe ko sese fun muhamadu lati s’eda iwe bi iru eyi fun. Lona keji, mo gbodo je ki e mo wipe ko seese fun eniyan k’eniyan kan lati seda re. E je ki a ro nipa eyi.

Kuran so bayi wipe,

“Lehinna A see ni omi gbologbolo sinu aye irorun Kan.”

[Kuran 23:13]

“O fi eje didi da enia.”

[Kuran 96:2]

Bawo ni anabi Muhamadu (pbuh) se mo pe omo inu maa n bere gegebi eje ti o dipo ti o si so mo ogiri inu ile omo iya re? Nje o ni ero irijin ni? Nje o ni ero iwo omo inu? Nje o ni awon ero iya aworan egungun ni? Bawo ni o se ni oye yi, oye ti o je wipe a sese se awari re ni bi ogoji odun ole meje seyin?

Bakanna, bawo ni O se mo wipe awon odo nla ni ipinya laarin won lati pin omi osa ati omi okun soto?

“Atipe On ni Eniti O mu awon odo meji san, okan dun ti odun gaan, ikeji ni iyo o si muro. O si fi gaga si arin awon mejeji ti a fi di won mo.”

[Kuran 25:53]

Bawo ni o se mo eyi?

“On ni Eniti O da oru ati osan ati orun ati osupa. Olukuluku won nluwe ninu ate (awowo).”

[Kuran 21:33]

Bawo ni o se mo pe Orun, Osupa ati awon aye n we koja ni aye ti a ti pase sile fun won? Bawo ni o se mo eyi? Ati bebelo- bawo ni o se mo awon nkan wonyi? Awon kan wonyi sese di awari ni nkan bi ogun odun le marun si ogbon odun seyin. Imo ero ati imo ijinle, sese se awari nkan wonyi. Bawo ni Muhamadu( PBUH) , ti o gbe ni egberun odun kan ati abo sehin – oluso aguntan eni ti ko kawe ti a to dagba ninu aginju, ti ko le ko tabi ka– bawo ni o se mo iru awon nkan bayi? Bawo ni o se le se nkanbayi? Ati bawo ni enikeni ti o gbe pelu re, siwaju re tabi lehin re, se le se nkan ti o sese di awari laipeyi. Eyi ko seese! Bawo ni okunrin kan ti ko kuro ni gbogbo agbegbe Arabia, okunrin kan ti ko wo okooju omi ri, ti o gbe ni egberun odun kan abo sehin –so iru kan bayi ti a sese se awari re ni aipe yi?

Pelu, ti eyi ko ba to, je ki so fun yin pe Kuran ni ori merin-leni adofa, o le ni egberun mefa ese. Ogorun awon eniyan ni o si wa ni igba Anabi Muhamadu (ALAAFIA WA PELU RE) ti won ha gbogbo iwe naa s’ori. Bawo ni eyi se sele? Nje o je akanda eniyan kan? Nje enikeni ha iwe ihinrere s’ori – enikeni? Nje enikeni ha iwe ofin s’ori, Orin Dafidi, Majemu Lailai, ati majemu Titun? Enikeni ko I ti se eyi. Popu papa ko I ti se.

Sugbon egberun lona egberun awon Musulumi lo wa loni ti won ti ha gbogbo iwe yi si ori. Eyi je ojuse gbogbo Musulumi. Ki I se fun awon die – sugbon gbogbo won! Kristiani melo ni e ti pade ti won ti ha gbogbo Bibeli s’ori? Kosi. E ko ti I pade Kristiani Kankan ti o ti ha gbogbo Bibeli s’ori , nitori e ko I ti pade Kristiani Kankan ti o mo ohun ti Bibeli wa nipa. Ki lo fa eyi? Nitori, awon Kristiani fun ara won, won ni o le ni edegberin orisirisi eya ijo, won si ni bi orisirisi eda bibeli mokandilogoji—pelu orisirisi iwe. Orisirisi awon ese ati orisirisi ori iwe. Won ko si si ni isokan. Nitorina, bawo ni won se fe ha ohun ti won ko fimo sokan si s’ori?

Eyi je awon die lara awon eri nipa Kuran. A si ti pa Kuran mo lai si ayipada bo ti wu ko kere mo ni opoplopo odun fun bi egberun odun kan ati abo sehin. Mi o soro lati da lebi. Mo ti je kristiani ri. Mo si se iwadi awon ohun wonyi fun ara mi. Emi naa ni mo n so awon nkan wonyi fun yin. Mo n si awon okuta kan soke fun yin lati wo abe re. O kun si owo yin!

Kan ro nipa gbogbo wonyi boya won je otito. Nje iwo yi o gba pe iwe yi je ogidi? Ati pe o je ara oto? Nje iwo yi o se olotito lati so be? Ni otito iwo yio so be, ti o ba je olotito. Iwo si je be. Ninu ara re, iwo ti wa si ipinnu yi. Opolopo awon ti ki I se Musulumi ni won ti wa si ipinnu bayi. Awon eniyan bi Benjamin Franklin, Thomas Jefferson, Napoleon Bonaparte, ati Winston Churchill, ki nkan ti d’aruko awon die. Opolopo si wa, mo si le tesiwaju lati maa daruko lo. Gbogbo won wa si ipinnu kanna. Boya won gba esin Islam ni gbangba tabi rara. Won wa si ipinnu kan yi—pe ko si iwe miran ni gbogbo agbaye yi ti o je ogidi bi kuran, orisun imo ati iwosan ati itosana.

Nisiyi ti a ti yanju ifesemule Kuran, e je ki a tun ye koko omiran wo: awon akori to se koko ninu Kuran. Isokan Olorun Oba, oruko re, iwa re, ibasepo laarin Olorun ati awon iseda re, ati bi o se ye ki awon eniyan motujo ibasepo naa. Ibasepo awon annabi ati awon ojise, ise iranse won ati ise won ni pato. Ati itenumo Muhamadu (pbuh) gegebi akoja awon annabi ati ojise. Ni riran awon eniyan leti wipe igbe aye yi kuru ati pipe won si aye ti o wa leyin aye yi. Aye leyin aye yi tumo si leyin ibi yi. Leyin ti o ba kuro ni ihin ti o lo ibomiran; N o so nipa asale yi. Sugbon lehin ti o ba ku ti o si fi aye yi sile, O n lo si ibikan, boya o gba atabi o ko gba; On lo sibe, o si ku si O lowo nitori A ti so fun O—bo ti e wu ki o ti koo. Nitori koko aye yi ki ise ki o kan joko nibi yi, ati leyin eyi ko ma se ohunkohun. Gbogbo ipa lo ni idi! O si wa si aye yi fun Idi ati eredi kan, o si gbodo ni ipa. O gbodo ni awon ipa kan! Ti o ko ba se ise O ko ni gba owo! Ti o ko ba kawe o ko ni tesiwaju! Ti o ko ba dagba gegebi omode o ko le di agbalagba! Ti o ko ba se ise o ko le ri ere! O ko le maa gbe ile aye lai ni ireti ati ku! O ko le ni ireti a ti ku lai ni ireti iboji! Atipe o ko si le ro pe iboji ni gbogbo re pari si. Eyi a tumo si wipe Olorun kan da O lasan. O ko si lo si ile iwe, o ko se ise, tabi o ko se ohunkohun, tabi o ko fe aya, o ko so awon omo re l’oruko ni aini idi kan pato. Bawo ni o se ma wa ro wipe lasan ni Olorun se awon nkan tire?

Ni igbiyanju lati jere okan ati ero eniyan, Kuran gba ona nla lati se alaye nipa ewa awon odo ati omi nla, awon igi ati ohun ogbin, eye ati kokoro, awon eranko buburu ati eranko kekere, awon oke nla ati awon ogbun ile, awon ofurufu, awon irawo oju orun, gbogbo agbaye, awon eja ati awon eranko inu ibu, eya ara eniyan, itan iseda eniyan, apejuwe aljanna ati ina apadi, ibi omo eniyan, ise gbogbo awon annabi ati awon ojise, ati ere idi iwalaye ninu Aye. Ati bi omode oluso agutan, ti a bi ti o si dagba ni aginju lai le ko tabi ka—bawo ni o sele se alaye awon nkan wonyi ti ko ri ri.

Ipa to yato ju lara Kuran ni wipe o fi idi awon iwe mimo ti isaju mule. Atipe, lehin ti o ba ye esin Islam wo, o gbodo pinnu lati di Musulumi, o ko nilo lati ro a ti paaro esin re! O ko paaro esin re… Wo, ti o ba jo, o ko ni so aso owo iyebiye $500 nu—o ko ni soonu! Wa mu lo ba telo wa si so fun ko ba e mu ko le wo o. Bakanna ni pelu igbagbo re, ola re, ife re , ife ti o ni si Jesu Kristi, isopo resi Olorun, ijosin re, isotito re ati ifaraji re si Olorun Oba – o ko ni so eyi nu! Wa di eyi mu! Sugbon, wa se atunse ni awon ibi ti o mo pe a ti fi otito han fun o! O tan!

Islam rorun: lati jeri pe ko si elomiran to to fun ijosin lehin Olorun atobiju. Ti mo ba bere lowo enikeni ninu yin lati jeri pe baba ohun ni baba oun—melo ninu yin lo ma so wipe, ‘beeni, baba mi ni baba mi; Omo mi ni omo mi; Aya mi ni aya mi; Emi na si ni emi.’ Bawo ni o se waje ti o nira fun yin lati jeri pe okan ni Atobiju ati wipe Olorun Atobiju Oun nikan, ati wipe Olorun Atobiju ni Oluwa re ati Eleda re? Ki lo de ti O gbe raga lati se eyi? Nje O n s’ogo ninu ara re? Nje O ni ohun kan ti Olorun ko ni? Tabi, O o do juru fun o? Eyi ni ibeere ti O ni lati bere lowo ara re.

Ti o ba ni anfani lati s’eto ohun gbogbo pelu eri okan re, ati lati s’eto ohun gbogbo pelu Olorun, nje iwo yi o se be? Ti iwo ba ni anfani lati so fun Olorun ko gba eyi ti o dara ninu iwa ati ise re, nje iwo yi o se be? Ti iwo ba ni anfani lati se eyi ki o to ku, ti o siro pe iwo yi o ku ni ale yi, nje iwo ki yi o kia jeri naa pe Olorun kan soso ni o wa? Ti o ba ro wipe iwo yi o ku ni ale yi ati pe ni iwaju re yi aljanna ati ni eyin re ina apadi, nje iwo ki yi o kia jeri pe Muhamadu ni ojise ikehin ti Olorun ati asoju gbogbo awon anabi? Iwo ki yi o kia jeri pe O je okan ninu awon ti a ko oruko won sile ninu iwe Olorun gegebi awon ti yonda ara won!

Sugbon, o lero wipe o si ni odun die lati gbe si. Ati pelu, o ko se tan lati maa gbadura lojojumo! Idi e ni wipe o lero wipe o si ni odun die lati gbe si. Sugbon melo ni ‘odun die?’ O to igba wo sehin ti ori re kun fun opolopo irun? O to igba wo sehin ti gbogbo irun ori re je dudu? Nisiyi, o ni irora ni orukun ati ejika re ati ni awon ibi omiran! O to igba wo sehin ti o si je omode, ti o n sare kiri ati ti on sere kiri lai ni ohunkohun lati ro? O to igba wo sehin? Ana ni! Beeni. Iwo yi o si ku l’ola. Nitorina, igba melo si ni o fe fi duro?

Isalm jeri pe Olorun alagbara julo ni Olorun, Olorun kan soso, Oun nikan ti ko l’obakan. Islam jeri pe awon malaika wa ti a ran jade pelu ise ifihan si awon anabi. Gbigbe awon ise iranse lo fun awon anabi. Di dari awon afefe, awon oke nla, awon okun, ati gbigba emi awon ti Olorun ni akoko won ti to lati ku. Islam jeri pe gbogbo awon anabi ati ojise Olorun je eniyan olododo. Ati wi pe a ran won jade lati odo Olorun oba lati so fun gbogbo eniyan gbe ojo idajo kan nbo fun gbogbo eda. Islam jeri pe, ati ibi ati ire gbogbo wa ni ikawo Olorun atobiju. Ni akotan, Islam jeri pe dajudaju igbende (ajinde) nbe lehin iku.

Islam da bi ile nla. Gbogbo ile ni a si gbodo ko pelu ipinle ati opomulero lati gbe ile naa duro. Opomulero ati ipinle kan. O si gbodo ko ile pelu awon ilana.

Awon ojuse ti o ye gbogbo Musulumi je ohun ti ko le rara, won si wa ni isori marun pere, eyi ti a mo si awon opo marun ti Islam: Igbagbo, Ijosin, Awe, Itore ati Irin ajo lo si ile mimo.

Eyi ti o se Pataki julo ninu liana Islam ni lati gbe igbagbo ninu Olorun kan soso ro. Eyi ni pe, lati ma gba olorun miran pelu Olorun. Lati ma se josin fun ohun miran lehin Olorun. Awon janma maa josin fun Olorun tara ki ise nipa se awon alufa tabi woli tabi eniyan mimo. O ko gbodo so ohunkohun nipa Olorun eyi ti o ko ni eto lati so. Lati ma se so wipe ‘o ni baba, omokunrin, omobinrin, iya, egbonkunrin, egbonbinrin, igbimo isakoso.’ Lati ma so ohunkohun nipa Olorun eyi ti o ko ni eto lati so. Ni igba ti o ba jeri, o se idajo fun ara re. O se idajo eyi ti o fe. Yala ko se idajo fun are re lo si Alafia ati aljanna, tabi ki o se idajo fun ara re lo si idojuru, iponju, ina apadi ati ijiya. O se idajo fun ara re.

Nitorina, bere lowo ara re, “Nje mo gbagbo pe Olorun kan soso ni o wa?” Ni igba ti o b a bere ibeere yi lowo ara re, o gbodo dahun, “Beeni, Mo gbagbo.” Wa beere ibeere ti o tele. Nje mo gbagbo pe Muhamadu ni ojise Olorun atobiju? “Beeni, Mo gbagbo.” Ti o ba gbagbo bayi, o ti di Musulumi. O ko nilo lati yi ohun ti o je pada. O kan nilo lati se atunse si ohun ti o je—ni ero re ati ise re.

Ni akotan, Mo beere ibeere kan pato: Nje oye ohun ti mo so fun yin ti ye yin? Ti o ba ti gba awon ohun ti mo so, O ti setan lati di Musulumi. Lati di Musulumi, o gbodo koko ka Shahada “Ijeri”; eyi ni lati jewo igbagbo re ninu Isokan Olorun ati igbagbo ninu Muhamadu gegebi anabi Olorun.

لا إله إلا الله محمد رسول الله
La ilaha illa-Allah, muhammad rasullulah

Ko si olorun miran lehin Olorun, Muhamadu si ni ojise Olorun.

Mo jeri pe Olorun kan soso lo wa
Mo jeri wipe Muhamadu ni ojise Olorun.

Te ihin lati gbo Shahada.

Ki Allah bukun fun wa. Ki Allah to wa sona. Mo fe so fun gbogbo awon onkawe yi ti ki ise Musulumi— Je olotito si ara re. Ro nipa ohun ti o ti ka. Mu alaye yi pelu re ki o si ronu le lori. Joko pelu Musulumi kan ki o si je ki won se alaye siwaju die si fun o nipa ewa Islam. Gbe igbese ti o tele!

Ni igba ti o ba setan lati gba Islam ki o si di Musulumi, we ara re ki o to di Musulumi. Gba Islam. Mo nipa Islam. Ki o si je anfani ti Allah fi fun o, nitori igbagbo ki I se ohun ti o le fi owo yepere mu. Ti o ko ba fi se iwa wu, wa so orun didun re nu. Ki Allah to wa sona. Ki Allah ran wa lowo. Mo si dupe fun anfani yi lati ba yin soro ni pase iwe yi.

Ni igba ti o ba setan lati gba Islam ki o si di Musulumi, we ara re ki o to di Musulumi. Gba Islam. Mo nipa Islam. Ki o si je anfani ti Allah fi fun o, nitori igbagbo ki I se ohun ti o le fi owo yepere mu. Ti o ko ba fi se iwa wu, wa so orun didun re nu. Ki Allah to wa sona. Ki Allah ran wa lowo. Mo si dupe fun anfani yi lati ba yin soro ni pase iwe yi.

السَّلاَمُ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَةُ اللهِ وَبَرَكَاتُهُ
Assalamu Alaikum wa rahmatullahi wa barakatuh
[Larubawa fun “Alaafia fun o ati pelu aanu Allah ati ibukun Re.”]

Ti o ba fe di Musulumi tabi ti o ba nilo alaye nipa Islam, jowo kowo ranse siwa lori info@islamicbulletin.org.


Wo / Sita yi Abala ni flipping Book

Bawo ni lati di a Musulumi fidio