Islam Igbagbo ati Àṣà

Itumo Islam

Awon Eko to se koko ninu Islam

Isokan awon omo Eniyan

Isokan Ise Iranse naa

Awon Opo Esin Islam

Awon Opo Igbagbo

Shariah Esin Islam (Awon Ofin Islam)

Awon ohun ti o ba ofin mu ati awon ti ko ba ofin mu ninu Islam

Ogun

Jihadi

Awon Obinrin ninu Islam

Iwoso

Awon asa isenbaye ti o tako Islam


Itumo Islam

Islam tumo si jijowo ara eni si awon Ofin ati Ife Olohun kan soso (Allah). Ijowo ara eni yi gbodo wa lati inu wa, lati inu igbagbo ti o jinle ninu Allah, laisiyemeji. O si gbodo wa lati inu ife, ifokantan ati ifeni.

Allah kii se olohun fun awon Musulumi nikan, sugbon Allah je Aseda gbogbo awon eda, ati pelu awon omo eniyan.

Annabi Muhamadu (Ki Alaafia wa Lori Re) je ojise Allah. Annabi Muhamadu (Ki Alaafia wa Lori Re) gba oro Allah (ifihan), lati owo angeli agba Jubril (Emi Mimo). Ninu ifihan yi ni Esin Islam wa.

Kuran je ojulowo akojo awon ifihan wonyi ni eda iwe. O je oro Allah ti a o yipada si awon omo eniyan.

Musulumije okunrin tabi obinrin ti o gbagbo ninu Allah ati Annabi Muhamadu (Ki Alaafia wa Lori Re) gegebi ojise Re ti o si njeri si igbagbo re ninu Islam gegebi esin re. A ko gbodo da “Musulumi” po pelu ”Arabu”; Musulumi je eniti o ntele esin Islam o si le wa lati eya yi o wu, sugbon Arabu je eya eniyan kan. Arabu le je elesin yi o wu, yala esin Kristiani, Islamu, esin Buddha, esin Hindu, tabi ko ma se esin rara, tabi eyikeyi esin. Awon Musulumi to je Arabu ko to ida mejidinlogun ninu ogorun awon Musulumi ni agbaye, ti o je bi okan ninu marun awon eniyan ninu aye tabi ka ni bilionu kan eniyan.

Islam je esin ti ko nira ti o si rorun lati se. O ni awon eko ati ofin ti o rorun ti ko si soro lati mo to je wipe o rorun lati mo fun omolehin tabi akeko esin naa. Islam gbagbo ninu awujo ti o bojumo ti o si laju. Islam ko si reti iwa rere ti ko seese lati owo awon omolehin re, sugbon o mo wipe eniyan ma nse asise won si ma ndese. Ko si eni ti o yo sile. Islam waasu alaafia, aanu, idajo, ifarada, idogba, ife, otito, idariji, suuru, iwa mimo, isotito ati isododo. Islam je esin ti o nwaasu ije okan Olohun, ije okan awon omo eniyan ati ije okan ise iranse naa.

Islam je esin ti o nwaasu ije okan Olohun, ije okan awon omo eniyan ati ije okan ise iranse naa.


Awon Eko to se koko ninu Islam

Ije okan Olohun: “Tawheed”
Awon Musulumi gbagbo wipe Olohun OKAN soso (Allah) ni o wa. Ninu Islam, lati gbagbo ninu Allah ko tumo si a ti gbagbo pe Allah wa nikan bikose lati gbagbo ninu awon iko Allah, ati lati josin Allah nikan, ati lati gboran si awon ase Allah. Tawheed pelu ije okan Oluwa, ije okan ijosin ati ije okan oruko ati awon iko:

A) Ije okan Oluwa: Lati gbagbo pe Allah NIKAN ni Aseda, Olupese ati Olupase.

B) Ije okan Ijosin: Lati gbagbo wipe Allah NIKAN ni Olohun ti o to fun ijosin, ati lati se gegebi Allah ti palase.

C) Ije okan awon Oruko Allah ati iko Re: Lati gbagbo wipe Allah Pe atipe awon Oruko Re ati Iwa re Pe gegebi ohun ti Allah so fun wa nipa ara re ninu Kuran, nini igbagbo wipe awon oruko ati iwa naa, ni pipe won, je ti Allah.

◊ Awon Musulumi gbagbo wipe KO si eniti oun ati Allah jo je Olohun yala angeli tabi eniyan. Allah so wipe:

“On ko ni fi enikankan kun ara ninu idajo Re.”

(Kuran Mimo 18:26)

◊ Awon Musulumi ko gbagbo wipe Allah nsun, tabi se are, tabi ku. Awon iko yi wa fun awon eda Allah. Allah ko ni ailera tabi are.

◊ Awon Musulumi ko gbagbo wipe a da awon eniyan ni aworan Allah.

◊ Awon Musulumi gbagbo wipe ko si alarina kan ti yio mu eniyan sunmo Allah tabi bebe funni. Won gbagbo wipe enikeni le se adura si Allah ki o si beere fun ohunkohun ti o ba fe.


Ije okan Omo Eniyan

◊ A da eniyan dogba niwaju Allah. Ko si enikan ti o ga ju enikeji lo fun idikidi bikose nipa iwa ododo ati iwa rere. O pon dandan ki awon Musulumi ki won o bowo fun iyi omo eniyan, laifise esin, eya, orile-ede, tabi ilu ti a gbe bi, gbogbo omo eniyan ni o ni iyi tire.

◊ A ko gbodo da eni keni lebi lori awon ohun ti won ko ni agbara le lori, bi iwa, awo, iwon, eya, ilera, ati bebelo. Islam ko wa wipe iyato awon omo eniyan je ami ola aanu Allah ati ewa iseda re. Annabi Mohamadu so wipe: “Ni otito Allah ko wo oju ati ara yin, sugbon o nwo okan ati awon iwa yin”.

◊ Ninu Islam ko si alufa, ipo alufa tabi awon eniyan mimo, ko si si eniti o ni irayesi majemu, sugbon awon ojogbon wa ti won ni oye Islam, ojuse won si ni lati se alaye Islam pelu ododo fun awon iyoku. AWON WONYI KAN JE OLUGBANINIYANJU.

◊ Islam ko awon eniyan ki won je oniwontuwonsi ninu igbe aye won. Awon Musulumi ko gbodo fi aye yi ba orun won je, tabi ki won tori ise aye yi mase ise sile fun orun.


Ije okan Ise-Iranse

Awon Musulumi gbagbo wipe Allah ran awon ojise si awon orile-ede Kankan lati iran de iran awon omo eniyan. Awon ojise wa pelu ise-iranse kanna: lati josin fun Olorun kan soso ati lati gboran si awon ase Re.

Aimokan omo eniyan nigba bibini. Awon Musulumi gbagbo wipe a bi omo eniyan laini ese won ko si jebi asise tabi ese enikeni. O di igba ti won ba balaga, ti won si momo da ese ni a o mu won je ere ise owo won ni aye yi ati aye ti mbo.

Ko si ese akoko ninu Islam. Awon Musulumi gbagbo wipe ati Adamo ati Hawau ni ajijo danwo, won jo da ese, awon mejeji ni won si jo se aigboran si Allah. Awon mejeji ni won ronu ti won si ronupiwada, atipe Allah si dariji awon mejeji.

Awon Musulumi gbagbo wipe ko si enikeni ti o jebi asise tabi ese elomiran, bo tile wu ki won je obi, omo; aya tabi oko.

Awon Musulumi gbagbo wipe idariji nbe nipase ironupiwada. Awon Musulumi ma ngbadura fun idariji tara lati odo Allah, laisi alarinna Kankan.

Igabla ninu Islam wa nipa igbagbo ati ise nikan. Awon mejeji lo papo, ki eniyan le ri igbala gba.


Awon Opo Islam

Awon opo marun ni o wa ninu Islam:

  1. Shahada (Ijeri)
  2. Salah (Adura)
  3. Sayem (Awe)
  4. Zakat (Itore)
  5. Hajj (Irin-ajo)

Shahada (Igbagbo)

Ijewo ifaraji ati eje wipe ko si orisa kan ayafi Allah, ati wipe Muhamadu si ni ojise Allah.

Wo Shahada Video fun o tọ pronunciation.

 

Salah (Ijosin to pon dandan[Adura])

O je ojuse gbogbo Musulumi, okunrin ati obinrin, lehin ti won ba ti balaga, lati se Solat (Adura) marun ni awon akoko ti a ti ya soto: – Owuro, Ojokanri, Osan, Irole, ati Asale. Eto kan ti a mo si Wudu (Fifo awon eya ara eni pelu omi) o je ohun ti a koko gbodo se siwaju Solat.

Rak'a

Aworan ti o wa loke yi je ti enikan ti o “rak’a”, eyi ni, enikan ti o duro, bere, dobale ati joko. Solati Kankan kun fun opolopo Rak’a. A ro awon Musulumi lati kirun ni mosalasi sugbon ti eyi ko ba seese, won le kirun nibikibi ti o ba mo; awon Musulumi ko le kirun ni baluwe.

Siyam (Awe)

Gbigba awe ni aarin osu Ramadan (osu kesan ti kalenda osupa) je lati igba ti oorun ba jade titi di igba ti oorun ba wo nikan o si je aigbodomase fun gbogbo agbalagba Musulumi ti o ni ilera ti o pe yala okunrin tabi obinrin. Awe gbigba je yiyera patapata kuro ninu jije ati mimu, fifa siga, jije gomu, ibalopo, ati jije ohunkohun. Ti enikeni ba n se are ti o si nilo lati lo ogun, oniitohun ko le gbawe. Igba awe tun je akoko lati se ara eni fun awon iwa buruku, bi ijiyan ati sisoro odi. Awon ti won nsare tabi ti won ko le gbawe nitori ailera tabi nitori ojo ori ni a yonda kuro ninu awe. Sugbon won gbodo bo awon alaini fun ojo Kankan ti won ba kunna lati gbawe. Awon obinrin ti won loyun tabi ti won nse nkan osu, tabi ti won nto omo, tabi enikeni ti o nri irin ajo, ni a tun yanda lati ma gbawe. Amo, ni igba ti nkan ba yipada fun won, won a san ojo ti won ti kunna pade nipa gbigba awe tabi nipa bibo awon alaini fun ojo awe Kankan ti won ba padanu.

Zakat (Itore)

Zakat je ojuse ododun fun gbogbo Musulumi, okunrin tabi obinrin, ti won ni ni odun ti o koja tan owo tabi ohun ini ti o koja ohun ti won nilo lo. A nreti pe ki won pin ida meji ati abo ninu ogorun ohun ini won ti o seku. A tun ma npe eyi ni owo-ori nitori o nran awon osise ijoba ti won ko ni anfani lati pa owo ni ona miran lowo.

Hajj (Irin-ajo)

Irin-ajo lo si Mokah, Saudi Arabia je ohun ti a nreti ni owo gbogbo Musulumi ti won ba ni owo re ati okun re ni ekan ni ojo aye won. Hajji ma nbere ni gbogbo odun ni osu Dul Hijjah; Dul Hijjah ni osu kejila ninu kalenda Islam (ti osupa). Hajj je irin-ajo emi nibiti Musulumi a ti gbagbe gbogbo ohun aye yi ti yio si fi okan re si odo Allah nikan.


Awon Opo Igbagbo

Ninu Islam, awon opo igbagbo mefa ni o wa: Igbagbo ninu Allah, awon Angeli Re, awon iwe Re si awon omo eniyan, awon Annabi ato Ojise Re, Ojo Idajo, ati Ayanmo.

1. Igbagbo ninu Olohun (Allah)

Islam ko wa wipe Olohun kan soso (Allah) ni o wa ti o si to fun ijosin ati igboran.

2. Igbagbo ninu awon Malaika (Awon Angeli)

Awon Musulumi gbagbo wipe Allah da awon eda ti a ko le f’oju ri bi awon Angeli. Awon Musulumi gbagbo ninu iwalaye won, oruko won, ise won, ati isapejuwe won gegebi a ti se alaye re ninu Kuran ati ninu Sunnah (awon Eko Annabi).

3. Igbagbo ninu awon Iwe Allah

Awon Musulumi gbagbo wipe Allah se ifihan iwe si awon omo eniyan lati owo awon Annabi Re ni igba de igba. Awon iwe wonyi wa lati orisun kanna; gbogbo won je ifihan at’oke wa. Awon Musulumi gbagbo ninu ojulowo awon iwe yi gegebi ati fihan. Awon iwe marun at’oke wa ti o se koko ni: 1) Awon Iwe Ibrahim; 2) Zaburi (Orin) ti a fihan fun Annabi Dauda; 3) Tawrah (Ofin) ti a fihan fun Annabi Musa; 4) Injil (Ihinrere) ti a fihan fun Annabi Isa; 5) Kuran ti a fihan fun Annabi Muhamadu.

4. Igbagbo ninu awon Annabi Allah

Awon Musulumi gbagbo wipe Allah ran awon Annabi wa si awon omo eniyan fun itoni won. Awon Musulumi gbagbo ninu iwalaye won, oruko won, ati ise-iranse won, gegebi Allah ati Annabi Re se so fun won. Awon Annabi ki-ise Olohun nitori Allah ni kan soso ni Olohun Atobiju. Gbogbo won je olododo, olotito, ati eniyan rere ti Allah yan lati je apeere fun awon omo eniyan, ninu oro ati ise won ni ibamu pelu ase at’oke wa.

5. Igbagbo ninu Yawm al-Qiyama (Ojo Idajo)

Awon Musulumi gbagbo wipe aye ti a wa ninu re yi yio wa si opin ni ojo kan, ni igba ti a o pa ohun gbogbo re. Ni ojo yi, a o ji gbogbo awon oku dide; Allah yio se idajo olukaluku gegebi ise owo re ni igba ti o wa laye iba je rere iba je buburu. Allah yi o san esan fun awon ti o ba hu iwa ododo ti o si se rere nipa riran won lo si Paradise (Aljannah). Allah yi o si dariji eni ti o ba wu ninu awon ti o se aigboran si ase Re, tabi ki o ju won si Ina Apadi (Jahannam).

6. Qada wal-Qada (Ayanmo, Ase At’oke wa)

Awon Musulumi gbagbo wipe ni iwon igba ti gbogbo agbaye wa ni abe ase ati idari Allah, ni idi eyi ohunkohun ti o ba sele ninu aye yi iba je kekere tabi nla wa ni abe isakoso Allah. Awon Musulumi fi okan won tan Allah, sugbon a ro won lati sa ipa won lai kan je ki nkan maa sele lasan. Irufe igbagbo ba yi ma nfi ni lokan bale agaga ni igba iponju. Sibe, Musulumi gbagbo wipe ohunkohun ti yio sele si eniyan, pelu papa iku, ko le se alaisele ni akoko re.


Shariah Islam (Awon Ofin Islam)

Shariah je liana at’oke wa ti o ndari Musulumi ninu igbesi aye re, a pin si ona meji: Ibada (Ilana Ijosin), ati Muamalat (eto ibanise). Koko Pataki ti o nse akoso awon ofin Islam ni Allah nipase awon ona meji; akoko ni Kuran, iwe Allah, ati ikeji ni Sunnah, ti-ise akojo toto ikosile awon oro, asa ti Annabi ati ohun ti awon alabarin re ba so tabi se ti ko lodi si.


Awon Ohun to ba ofin mu ati awon ohun ti ko ba ofin mu ninu Islam

Koko Pataki ti o nse akoso awon ohun ti o ba ofin mu ati ohun ti ko ba ofin mu ni wipe gbogbo ohun ni o ba ofin mu ayafi ti okan ninu awon ofin Islam ba ka si aibofin mu. Ninu Islam a ko gba wa laye lati mu oti lile, lo ogun, gba ele, ati awon iwa buruku miran. A ko tu gba wa laye lati je eran elede, tabi awon eranko ti o npa awon eranko miran je (iba je eye tabi eranko) ati gbogbo awon oku eran.


Ogun

Ogun ki ise ikan ninu ero Islam ki si se igbe aye ojo de ojo awon Musulumi; sugbon o je ohun ti a ma nlo ni igba ti ko ba si ona miran mo, a si ma nlo ni awon ona aranbara, ni igba ti gbogbo akitiyan lati fi alaafia petu si awo ati ija ba ti kuna. Ninu Islam, gbogbo eda eniyan ni o ni eto lati gbe igbe aye alaafia, laini fise esin yio wu ti won nse, ibi ti won ngbe tabi eya ti won ti wa. Ti awon ti ki ise Musulumi ba ngbe pelu awon Musulumi yala pelu alaafia tabi ni aisi-alaafia, ko si awijare Kankan fun awon Musulumi lati dide ogun, tabi ko oju ija, tabi tako eto won.


Jihadi

Ninu Islam, JIhadi ko tumo si “Ogun Mimo”. Ki siise igbe ogun soke si awon esin miran ati papa ki ise si awon Kristiani ati Ju, gegebi awon kan ti fe ki a rii. JIhadi tumo si “igbiyanju, itiraka tabi lilo agabra ju bi o ti ye lo ki aye eniyan ati awujo eniyan le dara si.” O ni iha atinuwa, iha awujo ati iha ijakadi.

– Ninu iha atinuwa ti Jihadi ni itiraka lodi si awon iwa ibi ti eniyan le fe wu; o je itiraka gbogbo Musulumi lati gbiyanju lati lodi si adanwo yala lati inu tabi lode si esekese. Eyi pelu itiraka lati bori isoro, inira, ise, ati idanwo.

– Ninu iha awujo ni itiraka lodi si iwa aidogba ni awujo ati lati le fi idi awujo mule ti o da lori ife, ola ati idogba. Ati lati pe awon eniyan ni awujo lati se rere ati lati korira ibi.

– Ni akotan, iha ijakadi ti jihad je ogun are ti a nlo lati koju ija si idukoko moni tabi lati ba alagbara amunisin ja, ati be papa, a ni lati tele awon ilana ti a gbe kale ninu Islam lati pa emi awon alaise mo ati lati dabo bo ayika.

– Islam ko fi aye gba eyikeyi iwa idukoko moni, iwa ipekun, iwa igba eesin lodi ati iwa imotan. Esin Islam fi owo si Pataki emi (a ri emi eni ti ki ise Musulumi bi ti eniti o je Mususlumi), ola, ohun ini, ati ominira lati yan ati se esin eyikeyi ti won yan laayo, ati awon iwa miran ni iwon igba ti awon iwa naa ko ba ti pa enikeni lara. Lati dukoko moni tabi tan eru kale ni awujo tabi lati pa eniyan lara; gbogbo iwonyi ni a ka si ese nla ninu Islam; Allah seto ijiya nla fun awon eniyan ti o ba wu irufe iwa wonyi.


Awon Obinrin ninu Islam

Islam ri obinrin gegebi eni ti o dagba, ti o kun oju iwon, ti o si dogba pelu okunrin, laisi eni ti ko le si ebi o si nko wipe ati okunrin ati obinrin ni a da lati owo Allah, won si dogba ni iwon ati iye.

Ni awon awujo kan, a ma nmu awon obinrin gegebi asa ati isedale, sugbon ninu Islam, a ma nmu obinrin pelu owo ati ola. Islam se itoju ola ati iyi awon obinrin, o si beere wipe ki a muu pelu ola ati iteriba. A ko gbodo yan-an je lonakona nitori ti o je obinrin, yala a gbodo se sii gegebi eniyan lai fi se wipe o je obinrin, nitori nipa ti jije obinrin re wa laarin oun ati oko re nikan.

Ninu Islam, igbeyawo ko le waye bikosepe obinrin naa fi owo si ati wipe ati san owo ori re fun-un. Islam fun oko ati iyawo ni aponle. Ojuse oko ni lati pese fun ebi re, ojuse aya si ni lati toju ile ati lati to awon omo. Awon wonyi je ojuse ti o se koko, sugbon ifowosowopo laarin oko ati aya se koko o si je ohun ti a gbawon niyanju lati ni.


Iwoso

Fun ati okunrin ati obinrin, Islam reti pe ki won o wo aso ti o dara, ti o bu iyi kunni, ti o mo ti o si wa ni iwontuwonsi.

A tun palase fun awon obinrin Musulumi lati maa lo okere tan Hijabu (ibori). Ni ile, pelu awon ebi re bi awon omo oko re, arakunrin re, egbonkunrin tabi aburokunrin baba re ati iya re, baba baba tabi baba iya ati awon okunrin miran (awon ebi re ti won ko le e fe), ati pelu awon obinrin yoku, obinrin Musulumi le bo aso iwosode re, o si ni anfani lati se ara re l’oso bi o ti wuu.

Awon aso ati eso ti ko b’ofin mu:

-Aso to funni, aso ti o fi ihoho han, aso ti o fi awon eya ara ti o jo mo ibalopo han, aso olowo iyebiye, aso iwe, ise ara loge tabi lilo pafumu ni ode, asomo irun ati irun wewe, wura ati siliki ni a ko fi aaye gba fun awon Okunrin Nikan, sugbon ti a fi aaye gba fun awon Obinrin.

Lapapo ninu Islam, ewa obinrin ati awon ise to jo mo ti ibalopo re ki ise fun isafihan ita gbangba.


Awon asa isenabye ti o tako Islam

Igbagbo ninu Islam (gegebi igbagbo ninu awon esin miran) da lori bi agbara igbagbo awon eniyan naa ba tiri. Ni igba miran, asa ati isenbaye ma ntako esin, tabi bo ori esin mole. Awon miran nwipe awon ohun nkan ninu asa tabi isenbaye won je ara esin, ni igba ti ko ribe. Tabi ki won se awon ohun ti ko ba esin Islam mu; sibe awon elomiran a ri eyi gegebi okan ninu awon idigi eko esin Islam.

Bakanna, a ko gbodo se idajo awon eko ati ise awon Musulumi bi ti awon esin omiran nitori awon ohun ti o ba ba ofin esin kan lo le lodi si ofin esin omiran.

Ni igba miran, iwa awon eniyan kan le bi awon elomiran ninu ni igba ti o je wipe won ko wu iru iwa bee lati bi won ninu. Fun apeere, Islam pase pe ki Musulumi dorikodo ni igba ti won ba nba eniyan soro gegebi ami iteriba. Eleyi le fa ibinu ni awon asa ti ifojukoju je ohun ti o se Pataki ni igbati ijiroro tabi oro siso ba nwaye.

Lati gbe po ni alaafi ati irepo ni aye yi, a gbodo mo wipe a da eniyan yato, won si tun yato ni awo ara won, ede won, ati ninu esin won, awon asa, ati awon isenbaye. Awon miran le yato, sugbon ko tumo si wipe won ko dara tabi won buru.