Ona Iyalenu Ti Mo Gba Se Awari Islam

Ni igba ti enikan beere lowo mi lai pe yi nipa bi mo se wo inu agbo Islam, enu ya mi die. Nitori n ko ro o ri wipe wi wa s’inu Islam je ohun kan to se koko. Kini igba akoko ti mo koko ye esin Katoliki wo? Igba wo ni mo koko di Musulumi? Idahun si awon ibeere yi nilo akoko fun mi lati ronu le won lori. Lati le dahun awon ibeere wonyi, mo ni lati bere lati ipinlese ki o le ye yin ibi ti mo de ni ikorita aye mi ki nto gba otito esin Islam. Mo di Musulumi ni omo odun meta-din-laadorin, mo si dupe l’owo Olohun nitori ti o ti bukun fun mi lati di oni gbagbo ninu esin Islam.

“Eniti Olohun ba fe fi ona mo yiosi igbaiya re fun Islam, eniti O ba fe fisile ninu isina yio se igbaiya re ni hiha (funfun) gadigadi bi (igbaiya) eniti ngunke lo si sanma. Bayi ni Olohun se egbin (iwa) fun awon eniti ko gbagbo”.

(Quran 6: 125)

A to mi dagba ni ile elesin Katoliki, mo je omo keji ninu omobinrin meta. Baba mi je eni ti on se ise asekara lojojumo.Yi o jade ni owuro kutukutu lojujumo, yi o si pada wole ni asale patapata. Gbogbo eyi je ki iya mi le duro nile bojuto awa omo. Ni ojo buruku kan, iya mi so fun wa wipe baba mi wa ninu ijamba oko kan. O ku lojiji aye wa si d’ori kodo. Pelu gbogbo awon iyipada ti on waye yi, iya mi so fun wa wipe oun a ni lati pada si n sise. Iya mi, ti o ti fi igba kan ri je onise iwosan noosi, ni lati bere si n sise pada lati le toju wa. O ri ise kan ile itoju alaisan kan, o si n se ise emeji lojumo lopo igba. Sugbon pelu ojuse titun yi, iya wa ko roju raye boju to wa mo. Bo tile je wipe o ran wa lo si ile iwe Katoliki, ise re ko je ki o bojuto awon omobinrin re.

Nitorina, pelu opolopo aaye funmi lati sere, mo ma n lo opolopo akoko pelu awon ore mi ni awon ibi isere ayika. Ni ibe ni mo ti pade okunrin Musulumi daada kan eyi ti o pada di oko mi. Iya mi ko mo wipe mo nlo akoko pelu okunrin yi. To be ge, ni igba ti mo so fun iya mi wipe mo setan lati se igbeyawo, nise ni iya mi kilo fun mi wipe ipinlese wa yato ati wipe a o ni isoro lojo ola. O so wipe ti a ba bimo lehin ola, wahala nipa esin yi o waye. Gegebi omo ogun odun, nko tile lero wipe a le ni isoro ki soro ninu igbeyawo wa. Mo ti yo fe inu mi si dun wipe mo ti ni eni kan ti yio maa toju mi. Oko mi ko kudun esin nigbana, ninu mi mo nro wipe n o le yi pada si esin Katoliki. Bo tile je wipe a ko wa lati eya kanna, mo ri ara mi gegebi eni ti o gba eya miran mora, mo si setan lati ko nipa eya titun.

Ohun gbogbo nlo dede fun opo odun die. Inu wa ndun, esin tabi eya ko si fi igba kankan da wahala sile. Olohun bukun fun wa pelu omokunrin arewa kan ati lehin opo odun die omobinrin arewa kan. Sibe, a n tesiwaju pelu igbe aye wa, mo si tun bere si ni ko awon omo mi losi sosi pelu mi. Oko mi ko dami lekun lati maa lo si ile ijosin ni gbogbo ojo aiku. Amo, lehin igba die ti mo ti nko awon omo wa lo si ile ijosin ni o so fun mi wipe on ko fe ki awon omo naa maa tele mi lo si sosi mo. Lotito, inu bi mi. “Sugbon Ki lo de?” Mo beere.”Eyikeyi esin o dara ju ki a ma se esin rara”mo so fun. N ko ri ewu to wa ninu ki ko won lo si sosi. Siwaju akoko yi, a ko tile ti fi igba kan ri soro nipa esin. Papa, nko ti e ti i ro ri boya esin omiran le wa leyin esin Katoliki. A bi mi gegebi Katoliki mo si gba wipe Katoliki nikan ni esin otito. Fun idi ti nko ti e le toka si, o da bi wipe lati ojo naa lo, mo bere si ni ri opolopo abukun. A bere si ni njiyan ni gbogbo igba- nipa ohunkohun. Nisiyi, nkan kekere di nla. Esin wa di ohun ariyanjiyan laarin wa. Iyato laarin eya wa di ohun ti a n jiyan le lori. A jiyan lori awon ana wa, eyi ti o buruju, a jiyan lori tito awon omo wa. Gbogbo awon ohun ti iya mi ti kilo fun mi nipa re ti bere si ni wa si imuse.

Alaafia ati isokan to kun laarin wa je ogbon, isotito, ibakedun, ati ife ti baba oko mi ni fun igbeyawo wa. Baba oko mi feran oko mi ati awon omo-omo re, be o si tun feran mi tokantokan gegebi omo re obinrin. O je eniti o mu esin Islam ni okukudun o si je ologbon okunrin. Ni igba na, nitori nko si ninu Islam, baba oko mi ni eni akoko ti o mu mi mo esin Islam. O ma ngba gbogbo adura, o ma ngbawe nigba Ramadani, o si ma npin fun awon alaini. Mo mo riri ife re si Olohun. Papa, baba oko mi ma n se toju awon alaini de bi wipe ni igba gbogbo ti o ba nbo nile lehin adura osan, o ma nmu alaini kan dani wa sile ki won le jo je ounje osan papo. Eyi ni, ni ojojumo.Titi di igba iku re ni eni odun marun-din-logorun, awon ebi ranti wipe o wu iwa yi titi di igba iku re.

Baba oko mi ko feran ariyanjiyan ti o ma nwaye laarin emi ati oko mi o si gba wa niyanju lati wa iyanju ki o ti di wipe awon omo wa yio maa je iya re. O gbiyanju karakara lati bawa wa iyanju. O kilo fun omo re ki o gba mi laye lati se esin mi, sugbon oro naa ti koja oro esin. O ti pin mi lemi mo si ti pinnu lati pinya. Ni igba ti mo bere lowo oko mi fun ipinya, o gba, ni ero wipe o le je ohun ti igbeyawo wa nilo na niyen. E mo oro yi, “Bi a ba jinna si ra, a ma mu ki anife ara wa si.” Amo, eyi ko sise fun wa. Ni pato, se ni ji jinna yi mu okan wa jinna sira si. Lehin ipinya yi, awa mejeji fe ipinya patapata a si gba lati ko ara wa sile. Bo tile je wipe mo fe ki awon omo mi maa gbe ni odo mi, awa mejeji fimo sokan pe o dara ki won maa gbe pelu baba won. Nitori ti O wa ni ipo ti o dara, nipa ti owo, lati to won ati lati fun won ni awon ohun itura lopolopo; awon ohun eyi ti nko si ni ipo lati fun won. Ni opolopo igba ni asale ni mo maa nro lati ri awon omo mi. Mo ko pada si odo iya mi mo si ma nri awon omo mi ni opin ose. Oko mi tele yio ko awon omo mi wa ni osan ojo eti a si wa ko won ni owuro ojo aiku. Bo tile je wipe iru eto yi ndun mi sugbon o dara ju ki o ma si rara lo.

Ni asale kankan ki nto lo sun, n o ka lati inu Bibeli. Ni igba ti awon omo mi ba wa lodo mi, maa ka lati inu Bibeli fun won, yala o ye won, tabi ko ye won. Ni igba ti mo ba ka lati inu Bibeli tan, ni awon asale kan, ma toro iranlowo lati owo Jesu, ni awon asale miran, ma a toro iranlowo lati owo awon angeli, ni asale miran awon enia mimo ati ni asale miran Maria wundia. Sugbon ni asale kan, ko si elomiran lati beere iranlowo lowo re mo, a ti beere lowo gbogbo awon enia mimo ti mo mo. Mo wa ni ‘nisiyi, a o beere lowo Olohun’. Omo mi okunrin wa ni ‘O dara, tani Olorun?’ Mo dahun mo ni ‘Oun ni o da O, ti o da Mi. O si wa pelu wa titi lai’. O si bere si ni ronu lori awon oro yi. Si alaaye mi, mo fi owo pa agbelebu aya mi. Mo wipe ‘Nisiyi Olohun seun’. O wo agbelebu naa o si wipe ‘Mama, tani eyi?’ Mo wipe, ‘Eyi ni Olohun. Oun ni omo Olohun’. O wipe ‘E sese so fun mi ni iseju kan sehin wipe Olohun wa titi, ki lo de eleyi ti ku?’ N ko ti ro eyi ri ni ile aye mi. O beere wipe nibo ni olohun eyi ti wa? Mo si wipe o wa lati inu Maria, Maria wundia. O wipe, ‘O, a bi ni igba kan sehin’. Mo ni, ‘hun, beeni’. Sugbon o wa wipe ‘Sugbon e wipe o wa titi lai. A ko bi, ko si le ku’. Omo mi okunrin eni odun mejo nisiyi beere lowo mi taara, “Mama, ki lo de ti e ko le bere iranlowo lodo Olohun?” O ya mi lenu, o si ka mi laya wipe omo mi le ma beere ibeere nipa esin mi.Mo so fun wipe mo ma nbeere lowo Olohun. Lai mo wipe omo yi yi o dagba yio si ma so fun mi ni igba gbogbo lati sin Olohun olotito kan soso. Olohun seun.

Lehin odun die, mo fe oko miran, mo si ko lo si Australia pelu oko mi titun. Oko mi atijo ko lo si Saudi Arabia pelu ebi re. O wu mi lati maa ri awon omo mi, sugbon ni Itali ni mo ti bere ebi titun ti mo si bi omobinrin meta. Sibe, ni gbogbo asale, n o gbadura, “Ni oruko Baba, ati ti Omo ati ti Emi Mimo.” Odun koja lo ni kiakia. Ni igba ooru kan, inu mi dun jojo nitori awon omo mi nbo wa ye mi wo. Opolopo ero lo wa si okan mi. Nje inu won yi o dun lati ri mi lehin opolopo odun? Kini a o so nipa re? Mo gbadura fun iranlowo. Gbogbo eru mi fo lo ni gbara ti mo ri awon omo mi ni ibudoko oko ofurufu. Isopo nla lo wa laye laarin iya ati awon omo re, ni se ni o dabi wipe odun die ni o si koja. Omo mi okunrin ni o soro ju ninu awon mejeji. O ran mi leti pe awon ki i je eran elede ati ounje ti o ba ni oti lile ninu. Mo si ran l’eti wipe nko ki n je eran elede nko si mu oti lile, iwa eyi ti mo ti nwu lati igba ti mo ti fe baba re. N o si gbiyanju lati ma se fi waini se ounje ni gbogbo igba ti won yi o lo pelu mi.

Ani igba oru ti o dara, a se mo mi mo o, won mo awon aburo won titun, a se ariya, a jade, a si luwe. Nko fe ki o wa si opin. Sugbon mo mo wipe won ni igbe aye won ni Saudi Arabia won si ni lati pada. Mo beere ibeere ti o le lowo omo mi obinrin bi iyawo baba re se n sesi, inu mi si dun ni igba ti o so wipe o mu oun gegebi omo.

Awon omo mi tun wa ye mi wo ni igba meji ototo lehin igba ooru naa. Ni igba ti omo mi okunrin pe omo odun mokanlelogun, o wa gbe pelu mi fun osu mefa. A ma njiyan nipa esin. Emi ati omo mi fi iwa jo ara wa, sugbon iyato to wa laarin wa naa tun po. Ninu ariyanjiyan, emi je alara gbigbona sugbon omo mi je eni tutu, nitorina oun ni o ma npetu simi nigba ti mo ba fe gbe oro gbona. A fi iwa oyaya, isore ati itore aanu jo ara wa. Ohun kan ti mo feran lara omo mi okunrin ni wipe o ni ifaraji ninu ohunkohun ti o ba da’wole. O dara, o si ni iwapele, sugbon o ni ipile ti o le, o si ma ngbiyanju lati se aseyori ohun ti o ba da’wole. O je eni ti o ma nronu jinle, ki i si pe lori isoro kankan. O ma n wa iyanju si isoro gbogbo ni kiakia. Mo tesiwaju lati maa gbadura pe omo mi yi o yipada si esin Katoliki. O wu mi gidgidi wipe yi o di alufa-mo l’ero wipe yi o je oniwasu daradara. O je omo daadaa, o si ni iberu Olorun. Awon wonyi je ami ti o dara fun alufa. Ni igba kan ti mo so fun wipe yi o di alufa daradara, o r’erin o si wipe, yi o rorun fun iya oun lati di Musulumi ju ki oun di alufa lo.

Lehin osu mefa, omo mi so fun mi pe oun fe lo si orile ede Amerika. O lo tedo si ilu Amerika o si n gbe ni Miami ni Florida. Mo di opo pelu omobinrin kekere kan ni ile. Omo mi okunrin fe ki nwa darapo mo oun ni Amerika, nitorina mo gba Amerika lo pelu omo mi obinrin omo odun metadinlogun. A feran Amerika lopolopo omobinrin mi si bere si ngbe igbe aye tire. Ohunkohun ko yipada fun emi ati omo mi okunrin-a si njiyan lori esin Islam ati Katoliki enikeni ko si fe ‘gba’. Ni igba miran, ti oro metalokan ba jeyo ti nko ni idahun si oro re, ma yara kuro lodo re. Inu a bi mi gidigidi ni ero wipe o ta abukun ba esin mi.

“Kilo de ti o ko le dabi gbogbo awon eniyan yoku,” Mo beere. “Awon Musulumi yoku gba mi bi mo se wa, won ko gbiyanju lati yi mi pada.” “Nko le dabi awon iyoku” o da mi lohun. “Mo ni fe re, emi ni omo re, mo si fe ko lo si aljanna.” Mo so fun wipe “mo nlo si Paradise-mo je obinrin rere, olotito enia, nko jale, nko puro nko si je eniyan lese.” Omo mi dahun, “Awon ohun wonyi se anfani ninu aye yi, sugbon ninu Kuran, a ko ni opo igba wipe Allah ko f’oriji Shirk (si sin olohun pupo). Kurani so wipe ese kan soso ti Olohun ko ni dariji ni siso olohun miran pelu Re, sugbon o le dari ese miran jin enikeni yi o wu.” O be mi ki nka ki nsi ko nipa ati ki nsi se awari Islam. O ko awon iwe wa ki nle ka ki nsi si okan mi paya, sugbon mo ko, a bi mi bi Katoliki no si ku gegebi Katoliki.

Fun odun mewa si, mo ngbe pelu omo mi okunrin, iyawo re ati ebi re. Mo si tun nfe lati lo akoko pelu omo mi obinrin ti o si ngbe ni Saudi Arabia. Ko rorun lati gba iwe irina. Omo mi dapara pe bi mo ba kan gba esin Islam, eyi yi o je iwe irina lati wo Saudi Arabia; wipe nigbana n o le gba iwe irina Umrah (iriin ajo lo si Mecca, Saudi Arabia). Mo so fun wipe nko ki se Musulumi. Lehin opo ise asekara ati iforoloyan, mo ri iwe irina gba lati lo se abewo si omo mi obinrin, on fun ra ra re ti di iya omo meta. Ki nto lo, omo mi okunrin di mo mi gidigidi o si so fun mi bi oun ti feran mi to ati bi oun se fe ki nwo Paradise. O tesiwaju lati so fun mi bi o ti se ni gbogbo ohun ti oun fe laye yato si wipe iya oun ki i se Musulumi. O so fun mi wipe oun ngbadura lojojumo si Olohun (Allah) pe ki O (SWT) yi okan mi pada lati gba Islam. Mo so fun wipe eyi ki yi o sele lailai.

Mo se abewo si omo mi obinrin ni orile ede Saudi Arabia, mo si ni ife si orile ede naa, bi oju ojo se ri ati awon enia re. Nko fe kuro lehin osu mefa, nitorina mo beere fun akoko die si. Mo ma ngbo Adhan (ipe si adura) ni emarun lojumo n o si ri bi awon onigbagbo a se ti oja won ti won a si koja lo fun adura. Bo tile je wipe eyi je ohun ti o wuri mi lori, mo tesiwaju lati maa ka Bibeli mi lowuro ati lasale, mo si nka rosiri mi nigba gbogbo. Ko si igba kankan ti yala omo mi obinrin tabi Musulumi kankan ba mi s’oro Islam tabi gbiyanju lati yi mi pada si Islam. Won bowo fun mi, won si gba mi laaye lati se esin mi.

Omo mi okunrin nbo ni Saudi Arabia lati be mi wo. Inu mi dun gidigidi-Okan mi tin fa si tipe. Ko pe to de lo tun bere si ni ba mi soro nipa esin nipa ije okan Olohun. Inu bi mi. Mo so fun wipe mo ti wa ni Saudi Arabia o le ni odun kan, enikeni ko si ti i ba mi soro nipa esin. Oun si re, ni asale keji pere ti o wolu, o ti sare bere si ni waasu fun mi. O toro aforiji o si so fun mi bi o ti wu oun to pe ki gba Islam. Mo si tun so fun wipe nko ni fi esin Kristiani sile. O beere lowo mi nipa metalokan ati bi mo sele gbagbo ninu ohun ti ko mu ogbon dani. O ran mi leti pe, emi papa ni ibeere lori eyi. Mo so fun wipe ohungbogbo ko gbodo mu ogbon dani-eniyan kan nilo igbagbo. O dabi wipe o gba alaye yi, inu mi dun, mo ti bori ninu iforowero nipa esin. Omo mi okunrin ni ki nse alaye ise iyanu Jesu fun ohun.Mo ro wipe mo n ni aseyori! Mo se alaye ibi iyanu ti Jesu, Maria Wundia, iku Jesu fun awon ese wa, Imi Olohun ninu Re, Jesu gegebi Olohun, Jesu gegebi omo Olohun. O dake ni gbogbo igba ti mo n soro, ko da mi lekun-omo mi okunrin, dake ke? O wa rora beere, “Mama, bi Jesu ba ku fun ese wa ni ojo eti ti o si ji dide lehin ojo meta ni ojo aiku, tani on se akoso aye fun awon ojo meta naa? Mama, se alaye eyi fun mi?” Mo ro nipa ogbon ti o wa ni idi ibeere yi, mo si mo wipe lowo yi ko mu laakaye lowo.

Mo wipe, “Jesu je omo Olohun. Jesu ati Olohun won si je okan soso.” Omo mi da mi lohun wipe, “Maalu ni omo; maalu kekere. Olongbo ni omo; olongbo kekere. Eniyan naa ni omo; eniyan kekere. Ni igba ti Olohun ba ni omo, kini eyi je? Olohun kekere? Ti o ba je be, nje e ni Olohun meji bi?” O tun wa beere, “Mama, nje iwo le di Olohun?” Mo so fun wipe iru ibeere wo ni eyi. Eniyan ko le di Olohun lailai. (Nisiyi, inu ti bere si ni bi mi gan.) Nigbana, o wipe, “Nje Jesu je eniyan bi?” Mo dahun mo ni, “Beeni.” O wa so wipe, “Nitorina, ko l eje Olohun lailai.” Ero wipe Olohun di eniyan naa je ero ti ko ni itumo. Ko dara to ki Olohun gbe awo iseda re wo, eyi tun mo si wipe o ti di eda owo re. Sugbon iseda je ise owo Aseda, ti Aseda ba gbe awo iseda re wo a tu mo si wipe Aseda ni o se eda ara re, nidi eyi a tu mo si wipe ko koko wa, ti ko ba si wa, ba wo ni o se le se eda awon ohun ti o da? Siwaju si, ti a ba se eda re, a tu mo si wipe o ni ibere, eyi ti o lodi si iwalaye titi lai re. Nipa alaye, iseda nilo Aseda. Olohun ko le nilo Aseda nitori oun ni Aseda. Nitorina, oro naa tako ara won. Eyi tako oye wipe a ko seda Olohun, ko nilo Aseda, oun si ni Aseda. Ni igba ti mo ri wipe nko ni idahun si oro re, mo dahun wipe, “Je ki nlo ro nipa idahun eyi.”

Ni irole ojo naa, mo ronu jinle lori ohun ti omo mi so. Ero wipe Jesu je omo Olohun ko ni itumo si mi mo. Nko si lee gba mo pe Jesu ati Olohun je nkankan naa. Ki nto lo sun ni asale naa, omo mi okunrin ni ki n gbadura si Olohun pe ki ohun ni kan to mi si ona otito. Mo seleri fun omo mi wipe n o fi tokantokan bere lowo Olohun fun idahun. Mo wo inu yara mi lo, mo si ka lati inu iwe ti omo mi ti fun mi. Lehin eyi, mo si Kurani Mimo mo si bere si ni kaa. Se ni o dabi wipe a ti gbe nkan kuro ni okan mi. Mo di eni oto. Mo ri otito ninu Islam. Kini mo ti n ba ja lati opolopo odun sehin?

Ni asale naa, mo gba adura si Olohun nikan, ki i se si Maria, ki i se si awon malaika tabi awon enia mimo tabi emi mimo. Si Olohun nikan ni mo kigbe si ti mo si beere fun itosona. Mo gbadura pe ti Islam ba je ona otito ki o yi mi lokan pada. Mo lo sun, ni owuro ojo keji, mo ji mo si so fun omo mi okunrin wipe mo setan lati gba Islam. Enu yaa. Awa mejeji bere si ni sukun. Omo mi obinrin ati omo omo mi obinrin naa jade, won si nwo mi bi mo ti n ke shahada (Ijewo igbagbo Musulumi ninu okan soso Olohun ati gbigba Muhamadu, (Ki Alaafia ati Ibukun Allah wa Lori Re) gegebi annabi Olohun) mi ni ede Lrubawa, Italiani ati ni Geesi.

أشهد أن لا إله إلاَّ الله و أشهد أن محمد رسول الله
“ASH-HADU ANLA ILAHA ILLA-ALLAH WA ASH-HADU ANNA MOHAMMADAN RASUL-ALLAH”.
“Ko si Olohun miran lehin Allah ati Muhamadu (PBUH) si ni ojise Re ati annabi ti o kehin”.

Fi eti si fidio Shahada video

 

Shahadah je ijewo igbagbo Musulumi ninu okan soso Olohun ati gbigba Muhamadu, (Ki Alaafia ati Ibukun Allah wa Lori Re) gegebi annabi Olohun. Mo di eni ti a ti yipada. Inu mi dun, a fi bi eni wipe enikan si iboju okunkun kuro ni oju mi. Gbogbo awon ti won ti mo mi ko gbagbo pe mo ti yipada. Ni igba miran, o je ohun iyalenu fun emi alara! Sugbon Isalm dun mo mi, o kun fun alaafia, o si fokanbale.

Lehin igba ti omo mi pada si orile ede Amerika, Mo ko lati le ka Surah-al-Fatiha ni ede Larubawa mo si ti ko lati le ma k’irun. Mo tesiwaju pelu igbesi aye mi bi ti ateyinwa; yato si wipe mo ti di Musulumi. Mo ma nferan lati lo si ibi ayeye ebi pelu omo mi obinrin, ati awon ayeye iyoku pelu. Mo ma nlo si ayeye igbeyawo awon ebi ati ore, ayeye henna, aqiqah (ikomo) ati isinku. Lehin osu mefa ti mo di Musulumi, mo wa ni ibi isinku kan ti o f’owo t okan mi ti o si tun fi di re mule bi Islam se ni ewa to. Odomodekunrin kan ku nipase aisan. Nigba ti omo mi nmura lati lo ki awon ebi naa, mo bere boya o mo awon ebi naa dada. O dahun wipe rara. “Kilo de ti o wa nlo?” Mo beere. “Nitori ebi naa ns’ofo o si je ojuse mi ninu Islam lati lo se iranlowo ki ranlowo ti mo ba le se.” Mo pinnu lati mura ati lati tele. Enu ya mi nitori opo eniyan ti o wa lati fi atilehin won han fun ebi naa. Ohun kan ti mo ri bi ebi naa se ns’ofo ni iru ewa ti o wa ninu Islam nitori opo eniyan ri gegebi ojuse won lati fi atilehin won han. Iru fe isele yi je ona miran ti o tun fi han mi ewa ti o wa ninu Islam.

Mo ti je musulumi fun odunmejo bayi, Alhamdullilahi. Lati igba naa, mo ti lo si Umrah lemeji pelu awon omo mi. Omo mi okunrin, omo mi obinrin ati emi ti se abewo lo si ilu Kabah (ni ilu Meka, Saudi Arabia). Ati mosalasi Annabi ti o wa ni Medinah. Mo sese se ayeye ojo ibi odun marunleladorin Alhamdullilahi. Ni gba miran, mo ma nro sehin awon inira ati irora okan ti mo ti ko ba omo mi okunrin, sugbon inu omo mi dun gidigan lati ri pe nipase oun mo wa sinu Islam. O wa wipe, Annabi (SAW) so fun enikan, “Paradise wa ni abe ese awon iya”. Itumo Aditi yi ni wipe o gbodo sin iya re ki o si toju re gidi. O daju pe, wi wa ni abe ese mi, paradise wa fun awa mejeji. Mo tun nro boya ti omo mi obinrin ba ti te mo mi die si boya nba ti di Musulumi kia. Sugbon omo mi okunrin ran mi leti wipe, Allah ni o mo ohun gbogbo. Oun (SWT) nkan ni o si le fun eniyan ni Hidaya (Itosona).

“Dajudaju ire ko le fi ona mo eniti o feran, sugbon Olohun lo nfi ona mo eniti O ba fe, atipe On lo mo ju nipa awon ti nwon mona.”

(Quran 28:56)

Ohun kan pataki ti Allah fi ke mi ni tito mi si ona Islam ati si so mi di Musulumi, InshAllah n o wo inu aljanna pelu omo mi.
« AMEEN> »